Lizzy Anjorin ti dásí ìjà fún Oduduwa Republic tí Sunday Igboho ń darí ẹ̀

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Lizzyanjorin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja oṣere elere, Lizzy Anjorin naa ti da si ọrọ ijijagbara Oduduwa Republic tawn kan korajọ ti wọn n ja fun.

Lori ọrọ ijijagbara Oduduwa Republic ti ajafẹtọ ọmọniyan, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, wa lara awọn to n ṣagbatẹru rẹ.

Lori eto fidio kan ti Lizzy ṣe loju opo ayelujara rẹ to si n ba awọn eeyan sọrọ ni bo ṣe n ṣe eto naa lọ, o ni awọn to n sọ pe Naijiria ko lọ si waju, ir ni wọn n pa tori pe Naijiria ti ṣe daadaa lọjọ ori rẹ yii.

O ni iwoye ti oun loun n sọ nipa Oduduwa Republic, awọn to n ko o jọ ati awọn ti yoo gbe nibẹ.

Lizzy ni lootọ, igbesẹ to dara ni to si ṣee ṣe yọri ṣugbọn o ni bawo lo ṣe fẹ jẹ aṣeyọri gan.

Lakọkọ, o ni bi ipinlẹ Eko yoo ba wa lara ilu ti yoo dara pọ mọ orilẹede ti wọn n ja fun yii to si jẹ wipe ọpọlọpọ ẹya lo n gbe ni Eko, "nibo lẹ fẹ ki awọn ẹya Ibo lọ?".

O ni awọn ibi kan wa to jẹ wi pe awọn eeyan jankanjankan lo n gbe nibẹ to si jẹ wipe odidi ida ọgọrin ni ẹya Ibo ti Hausa ati Yoruba pin iwọnba to ku.

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Lizzy anjorin

Lizzy ni ọpọ ọmọ Ibo to jẹ oniṣowo lo ṣiṣẹ ti wọn fi kọ ile fi ra ilẹ ko si si ẹya Ibo ti yoo jade tabuku ba wọn ṣugbọn o ni to ba ti jẹ ọmọ Yoruba ni, wọn a ni aṣẹwo lo n ṣe to fi n ri owo.

"Ọjọ wo lẹ ti ri oniroyin ọmọ Yibo to n fi irinṣẹ tabi oju opo wọn ba ti ọmọ Yibo ara wọn jẹ. Ṣé àwọn aṣẹwo, ọmọ ole, ọmọ Yahoo lẹ fẹ ko si Oduduwa Republic".

Lori iṣẹ Tiatia, o ni ṣe wọn ti ri ọrọ awọn to n ji iṣẹ fiimu awọn lati ṣe ẹda rẹ yanju tabi ko wọn kuro ni Alaba ni Eko nibi to jẹ gbajugbaja ibudo ọja fiimu ki wọn to maa sọrọ Oduduwa Republic.

"To ba ti jẹ pe ibajẹ lo maa n ṣe kaakiri, oo le kọ iel kankan, ma tilẹ dan an wo". Ẹni pato ti Lizzy n bawi pẹlu ọrọ yii ko ye.

O ni awọn eeyan jankanjankan nilẹ yoruba to yẹ ko wa niwaju ninu ọrọ yii, awn to n korajọ ti baba ba wọn jẹ tori ohun elo ti awọn ọmọ Yoruba ni fun iru nkan bayii, wọn fi n ba ara wọn jẹ ni dipo ki wn fi tun ara wọn ṣe.

Lizzy Anjorin ni ṣiṣe ilana ọtun, eto ọtun pẹlu ohun kan ṣoṣo.

Lori ọrọ jija fitafita fun nkan, o ni daju daju awọn kan lo maa fi ẹmi wọn ṣe etutu tori jija fun ominira bẹẹ si ni awọn kan lo maa gba ade ijafita fita naa. O fi ara rẹ ṣapejuwe ẹni to ti la jija fitafita kọja laye.

Lizzy gboriyin fun iṣẹ ti Sunday Igboho n ṣe to fi mọ iha ti Iba Gani Adams naa n kọ si ọrọ yii.

Àkọlé fídíò, Wo Adigun ọmọ ọdún mẹ́rin tí òwe Yorùbá àti ìtúmọ̀ gbó lẹ́nu rẹ̀ ju tìrẹ̀ lọ

Awọn ibeere fun ẹkọ latẹnu Lizzy

Ṣe awa to jẹ wipe a gbọ jọ ẹnikan agba oṣika ni wa, ṣe awa la n lọ si Oodua Republic?

Ṣe koo to jẹun, ṣe o ro o pe ṣe awọn to n tẹle ẹ ti jẹun gẹgẹ bi adari?

Ṣe o mọ pe too ba fun awọn eeyan lounjẹ lai si ẹran, o n kọ wọn ni iṣẹ ni?

Ṣe a ti dan ara wa wo, ṣe a le gbe nibẹ?

Ṣe awa Oduduwa Republic naa lẹ maa ki awọn eeyan dudu nilu Oyinbo ti wọn a ṣe bii pe wọn ko gbọ Yoruba?

Ọrọ nipa Lizzy Anjorin gangan lori eto

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Lizzyanjorin

Lori eto ti gbajugbaja oṣere yii ti n sọrọ eyi to yẹ ko jẹ nipa akori eto rẹ nikan sọọọ naa lo ti n da awọn ọlọtẹ to darapọ mọ eto lohun.

Lizzy ni lara awọn to wa n wo eto naa, onibara eleebu ni ni tirẹ to jẹ wipe ti ko ba tii bu oun ko le jẹun.

"Boo ba ṣe ibi si mi too ro wipe aye wa lẹyin rẹ, Ọlọrun ko le si lẹyin ẹ". O ni awọn kan gbogbo agbara ti wọn ni ki wọn ṣaa fi ba ti ẹni to n ga jẹ ni. Lo ba dupẹ lọwọ rẹ pe o korira oun.

"Too ba sọrọ mi laidaa, ko tu irun lara mi tori awọn ọrẹ rẹ gan le ma sọ nkan ti yoo mu inu bi ẹ ṣugbọn latẹnu awọn to n sọrọ ẹ laida, ori ẹ a pe".

Lizzy ni ti aarin oun ati Ọlọrun ba ṣaa ti dan mọran, o ti to fun oun. Torinaa bi kii ba ṣe ti ẹni to sọ ọrọ ibanujẹ si oun, oun o ni yipada.

"Ẹ lọ bere mi daadaa, mi o ki n ja mi o ki n binu ṣugbọn too ba so okun mi mi mu,

Lara ohun ti Lizzy tun mnu ba ni wipe oun kii ko ọrẹ tori ko f ki wọn kọ oun ni ikọkukọ. O fi kun un wipe oun ni afojusun ati ipo ti oun fẹ de laye tori igba kan wa ti oun lowo lọwọ ṣugbọn oun o le jẹun ẹgbẹrun kan naira.

"Bi ida aadọrun awọn ọrẹ rẹ ba fẹran rẹ, o tumọ si pe oo ṣe daadaa to".

Koko ọrọ ti Lizzy Anjorin tẹnu mọ ju ni wipe ki eeyan ma naani kikorira ọrọ awọn eeyan to ba korira rẹ tori ikorira wọn gan lee gbe ẹ dide.