Internet fraud: Ọwọ́ EFCC tẹ afurasú 'Yahoo boy' Olawale àti pásítọ̀ CAC tó lu Hayatou ní jìbìtì N12.7m

Adebayo Olawale ati Gbenga Moses Adesoju

Oríṣun àwòrán, Twitter/EFCC Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati iṣowo ilu kumọkumọ, EFCC ti mu ọdọkunrin kan, Adebayo Olawale ati pasitọ ijọ CAC Ile Ife, Gbenga Moses Adesoju lori ẹsun pe wọn lu Umar Hayatu ọmọ ipinlẹ Gombe ni jibiti owo to din diẹ ni miliọnu mẹtala naira(N12.7m).

Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren lo fọrọ yii lede loju opo ayelujara Twitter ati Facebook ajọ naa.

Ọgbẹni Uwujaren ṣalaaye pe ọwọ tẹ Olawale ati pasitọ rẹ ni Ile Ife lẹyin tawọn ẹbi Hayatou fi ọrọ jibiti naa to ajọ EFCC leti.

Ajọ EFCC ṣalaye pe awọn afurasi mejeeji naa gbimọ pọ lu Hayatou ni jibiti lori ayelujara ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ lẹyin ti wọn parọ fun un pe o jẹ ẹbun ọkọ ati awọn foonu olowo nla pẹlu iṣẹ to n doju ti iṣẹ.

Ninu atẹjade ti EFCC fi sita, ajọ naa sọ pe Olawale lo ayederu oju opo Williams Angellina ati Omolola Adebayo lati tan Hayatou jẹ wi pe baba oun ni ileeṣẹ loke okun.

O tun parọ fun Hayatou pe baba oun ṣetan lati yan an si ipo adari ni ẹka ileeṣẹ naa to wa ni ilu Eko ni Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

EFCC ni Olawale tun fi ọpọ ayederu fọto ile ati ọkọ ti wọn yoo fun Hayatou ranṣẹ si i.

Bakan naa ni Olawale tun parọ fun Hayatou pe oun yoo fun lẹbun ẹgbẹrun un lọna ọgbọn owo dọla($30,000) ati ''iPhone'' olowo iyebiye to fi mọ goolu.

Iwadii ajọ EFCC lo fihan pe owo to din diẹ ni miliọnu mẹtala naira(N12.7m) to gba lọwọ Hayatou wa ninu apo ikowosi Olawale ni banaki kan to n lo.

EFCC ṣlaaye pe afurasi keji, pasitọ Adesoju naa gba ẹbun ọkọ BMW kan, ilẹ ati ọpọ tabua ninu owo ti Olawale gba lọwọ Hayatou.

Ajọ EFCC ni awọn mejeji yoo foju ba ileẹjọ lẹyin ti iṣẹ iwadii ba ti pari.