Ondo Governorship Election: Ọ̀pọ̀ dúkìá àti mọ́tò bíí 15 làwọn jàǹdùkú bàjẹ́

Laasigbo oselu

Oríṣun àwòrán, Others

Ileesẹ slọpaa nipinlẹ Ondo ti fidi rẹ mulẹ pe laasigbo oselu waye lọjọbọnilu Ondo nipnilẹ Ondo

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro ni ninu aawọn naa ni ọpọ eeyan ti fara pa amọ ko si ẹni to ku ninu laasigbo naa.

"Ileesẹ ọlọpaa ti n se iwadii nipa oun to fa isẹlẹ naa, ti a ko si lee se alaye awọn ẹgbẹ oselu ti aje ọrọ naa si mọ lori nitori o ti di ija igboro."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikoro ni ọwọ ọlọpaa ti ba awọn janduku ẹda kan to lọwọ ninu rogbodiyan ọhun, ti iwadii si tun n lọ lọwọ lati mu awọn afurasi ọdaran miran si.

Iroyin kan fikun pe ọps dukia ni wọn baana lasiko ija igboro to jẹ ti oselu naa, ko si din ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹẹdogun to bajẹ.

Àkọlé fídíò, Rape cases in Nigeria: Ọmọ ọdun 5 àti 14 ni Kalu wà nígbà tí obìnrin fipá ba lòpọ̀

Sugbọn ileesẹ ọlọpa ko tii le sọ ohun to sokunfa isẹlẹ naa.