Oyo state paternity leave: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ lórí bí àwọn ọkùnrin ṣe leè máa gba ìsinmi ìtọ́mọ (Paternity leave)

awọn lọkọlaya kan

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni igbesẹ ti bẹrẹ igbesẹ lati rii pe awọn ọkunrin ti iyawo wọn bimọ naa n gba isinmi itọju ọmọ ti oyinbo n pe ni Paternity leave.

Kọmiṣọnna fun ọrọ awọn obinrin ati idagbasoke ilu, Alaaja Faosat Sanni to ṣalaye ọrọ naa ni Ibadan.

O tun fi kun un pe isinmi itọmọ ti ijọba n fun awọn obinrin to loyun tabi to n tọju ọmọ yoo kuro ni oṣu mẹrin si mẹfa fun awọn to n jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ.

Komisonna ni afikun iye akoko isinmi itọju ọmọ naa ṣe pataki nitori ati fun awọn ọmọ ni itọju to peye ki awọn iya wọn naa le e tọju ara wọn.

O ni ijọba ipinlẹ naa ti n fọnrere idaabobo to peye fun awọn smọde ati awọn obinrin nitori naa gbogbo igbesẹ to ba yẹ naa ni wọn yoo gbe lati fi idi eyi mulẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá