Boko Haram, ISWAP in Borno: Islamic State West Africa Province ni àwọn mọ̀ọ́mọ̀ pa ṣọ́jà méje náà ni

aWọN ọmọ ikọ ISWAP

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn alákatakítí Islamic State West Africa Province kéde pé wọ́n tún ti pa àwọn ṣọ́jà ní Kukawa ni ipinlẹ̀ Borno to sunmọ orilẹ-ede Lake Chad

ISWAP sọ pe oun ti ṣeku pa ọmọ ogun meje ni ila oorun ariwa Naijiria nilu ti wọn n pe ni Kukawa.

Koda, o ni ọwọ oun ti tẹ awọn miran ti oun mu mọlẹ nibẹ.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, ni wọn ti ni awọn ṣe ikọlu si ibudo ọmọ ogun ilẹ to wa nibẹ nibi ti wọn ti ṣe awọn miran leṣe.

Awọn alakatakiti Islamic West Africa Province yii ni iroyin ni wọn ti gba awọn ọkọ ijagun awọn ọmọ ogun ilẹ Naijira ati awọn irinṣẹ ogun miran lọwọ awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria bayii.

Wọn ko sọ boya wọn ko awọn ara ilu mọ awọn ti wọn ko nibẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria naa ti fi atẹjade sita ni eyi ti wọn ti ni tootọ ni awọn alakatakiti Islamic West Africa Province ṣe ikọlu sibudo ọmọ ogun ilẹ ni Kukawa.

Sugbọn ileeṣẹ ologun Naijiria ni irọ ni pe ISWAP ṣọṣẹ bi wọn ṣe sọ.

Koda, ileeṣẹ ologun ni a\won ọmọ ogun Naijiria fakọyọ ti wọn si kọlu awọn oniṣẹ ibi yii pupọ.

Ileeṣẹ ologun ni ṣọja mẹta lo fara gbọgbẹ ninu ikọlu naa.

Ogagun John Enenche to jẹ agbẹnusọ fun ileṣẹ ologun sọ pe awọn ọmọ ogun pa Boko haram mẹjọ nigba ti ọpọ salọ pẹlu ọgbẹ to pọ.

aWọN ọmọ ikọ ISWAP

Oríṣun àwòrán, others

aWọN ọmọ ikọ ISWAP

Oríṣun àwòrán, others

Ki lo ti ṣẹwlẹ sẹyin?

Boko Haram ṣọṣẹ́ ní Borno, wọ́n sé àwọn èèyàn mọ́lé ní Kukawa

Agbègbè Kukawa ni ipinlẹ Borno ni àwọn oníṣẹ́ ibi yìí ti ṣọṣẹ́ báyìí

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ni ila oorun ariwa Naijiria ni awọn oniṣẹ ibi yii kọlu ni ipinlẹ Borno.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ni ila oorun ariwa Naijiria ni awọn oniṣẹ ibi yii kọlu ni ipinlẹ Borno.

Koda, wọn ni niṣe ni awọn Boko Haram se awọn eniyan Kukawa mọ ile.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, awọn ọmọ ogun ilẹ ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Ko i tii pe ọjọ melo ti awọn eeyan gba ominira pada wa si agbegbe Kukawa yii nipinlẹ Borno lẹyin ti wọn ti kọkọ sa asala fun ẹmi wọn kuro nibẹ ri.

Bẹẹ laipẹ ni ijọba Naijiria ni wọn tun igbesi aye awọn Boko haram to ronu piwada ṣe ti wọn si tun tu wọn silẹ lati maa lọ ni alaafia pe wọn ti yipada kuro ninu iṣẹ ibi wọn.

BBC ko tii ri awọn ifitonileti ni ẹkunrẹrẹ lori ohun to n ṣẹlẹ bayii ni agbegbe Kukawa ni ipinlẹ Borno.

Titi di asiko yii ko tii si ẹ\ro ibanisọrọ to ṣiṣẹ ni agbegbe naa lati fi ba awọn eeyan naa sọrọ ni kikun nitori pe lati ọdun mẹwaa sẹyin ni ogun yii ti n ba wọn finra..

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Awọn iroyin ikọlu awọn Boko haram yii fihan pe wọn yi n ṣọṣẹ to pọ ni ila oorun ariwa Naijiria lai nii fi ṣe iṣẹ akọni ti wọn ni awon ọmọ ogun ilẹ n ṣe ni ẹjkun naa lati bori awọn oniṣẹ ibi ọhun.

Agbegbe Kukawa ko fi bẹẹ jina si orilẹ-ede Lake Chad.

Lọsẹ to kọja diẹ ni ọpọlọpọ aṣatipo dari pada wa sisle ni ẹkun yii pe ogun ti tan laimọ pe Boko haram n pada bọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

O le ni miliọnu meji eeyan ni ila oorun ariwa Naijira ti wọn ti di aṣatipo lataari ikọlu Boko haram ni ẹkun yii

Ajọ iṣọkan agbaye, United Nations ti kilọ [pe iṣẹ nla lo ṣi wa niwaju Naijiria nitori pe ohun eelo iranwọ kotii de ọwọ idaji awọn to nilo rẹ gẹgẹ bii aṣatipo.

Saaju ni iroyin kan ti ni awọn alakatakiti ẹsin ISWAP kọlu awọn ọmọ ogun ni Chad tẹlẹ.