Taribo West: Àwọn aláìní ní Italy ní mò ń fi owó ìjọ mi ràn lọ́wọ́

Taribo West

Oríṣun àwòrán, Others

Ilumọọka agbabọọlu ọmọ Naijiria to ti di ajihinrere bayii, Taribo West ti salaye lori bo se n gba awọn ọmọ Naijiria, to lọ se asẹwo lorilẹede Italy, silẹ.

Agbabọọlu tẹlẹ naa, lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ ni ọpọ awọn ọmọ ilẹ yii ti ko rile gbe, atawọn asẹwo to wa nilu Milan ni oun n se iranlọwọ fun.

Taribo ni ijọ oun, The Storm Miracle Ministry of All Nations, ni oun n lo lati tọ awọn eeyan naa sọna nipa igbe aye rere to yẹ ki wọn gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ọlọrun lo sọ fun wa pe ka lo ohun gbogbo ta ba ri ko jọ lati inu owo to n wọle fun wa, fi mu igbe aye dẹrun fawọn eeyan to ku diẹ kaa to fun.

Bakan naa, gbogbo awọn eeyan ti awujọ ti ropin pe ko le se rere nitori ko rọrun lati gbe nilẹ Yuroopu, o dabi ilẹ awọn to n se atipo ọrọ aje ni."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Taribo West fikun pe ọpọ awọn eeyan ti ijọ oun ti se iranlọwọ fun, tawọn si tun doola ẹmi wọn loke okun, si ni oun maa n kan si.

Italy fáìnì ọmọ Nàìjíríà tó ń gbálẹ̀ àdúgbò lọ́fẹ̀ẹ́

Ijọba orilẹede Italy ti fagile faani ti wọn fun ọmọ orilẹede Naijiria kan to n gba ilẹ awọn adugbo kọọkan lai gba aṣẹ.

Iroyin sọ pe ni ilu Venice ni ọmọ ọkunrin naa ti n gba ilẹ adugbo ti igbimọ alaṣẹ to wa nibẹ si ni ko gba aṣẹ ko to maa gba a.

Ni ọlọpaa agbegbe Mestre lẹba Venice ba wọn ọn ni faini to fẹrẹẹ to $400 (iyẹn nkan bii N144,000).

Àkọlé fídíò, African Migrants: Awọn arinrinajo sọ iriri wọn lọ si ilẹ Amerika

Lẹyin ọpọlọpọ ikun sinu latọdọ awn ara adugbo, awọn alaṣẹ gba pe awọn ti fun arakunrin naa ni ijiya to pọ ju.

O ti di ohun to wọpọ ki awọn arinrinajo to lọ si orilẹede italy maa gba idọti awọn adugbo orilẹede naa.

Wọn ni o pe awọn lati lọwọ si idagbasoke agbegbe naa ju ki awọn maa tọrọ owo kiri lọ.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa agbegbe fi ẹsun kan ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa ti orukọ rẹ n jẹ Monday pe o n tọju adugbo lai gba aṣẹ lọwọ awọn alakoso ibẹ.

Agbẹjọro kan, Matteo D'Angelo to da eto iranwọ fun Ọgbẹni Monday silẹ lori ayelujara lati san faani rẹ sọ pe ijiya ti wọn fun un ko boju mu rara.

Iroyin sọ pe Ọgbẹni D'Angelo ko owo ti wọn ko jọ lori ipolongo ori ayelujara fun Ọgbẹni Monday lati fi di iya ti awọn ọlọpaa fi jẹ ẹ.

Àkọlé fídíò, Kí ni Yorùbá ń pe ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn Àlàbá?