Olufunke Oshonaike: Ewu ń bẹ fún àwọn obìnrin tó ń fẹ́ ọkọ ọlọ́kọ

Oríṣun àwòrán, Google
Agbabọọlu ẹlẹyin Table Tennis to ti gbami ẹyẹ nilẹ Afirika ri, Olufunke Oshonaike ti bu ẹnu ate lu bi awọn ọkunrin to ni iyawo sile ṣe n bere fun ibasepọ pẹlu oun.
Olufunke to sọ eleyii lori oju opo Facebook rẹ, sọ wi pe oun ti sọ ifẹ fun igbeyawo nu, lẹyin ti ọpọlọpọ ọrọ ifẹ oun ti forisanpọn.
Ninu ọrọ rẹ, Olufunke sọ wi pe awọn ọkunrin ti foju oun wina nitori ọpọlọpọ aisotitọ ati ododo ti wọn ti fi ba oun lo.
O fi kun un wi pe, ọkọ ti oun fi silẹ, Kevin irabor lo fẹ ẹlomiran lẹyin ti awọn ṣe igbeyawo, ti oun si ti bimọ meji fun un.
Bẹẹ lo kilọ fun awọn obinrin pe ki wọn ranti pe, ko si oun ti eniyan ṣe silẹ, ti ko ni ba.
Arabinrin naa wa parọwa si awọn obinrin lati ye fẹ ọkọ ọlọkọ, ki idile lee gboro sii, nitori ewu ti o n fa ninu idile ko kere rara.









