Trump impeachment: Àṣírí tùú, àkọsílẹ fihàn bí Trump ṣé béèrè iranwọ lọ́wọ́ ààrẹ Ukraine

Aworan Aarẹ Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Wọn ti bẹrẹ igbesẹ lati yẹ aga nidi aarẹ Trump

Lorileede Amẹrika, ẹgbẹ oṣelu Democratic Party ti bẹrẹ iwaadi lati ṣe itọpipin aarẹ Trump, eleyi to le ja si ki wọn yọ nipo.

Igbesẹ naa ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan Trump pe, o lo ipo rẹ lati wa iranlọwọ orilẹede miran ki wọn ba le ṣakoba falatako rẹ.

Igbeṣẹ iwaadi irufẹ eleyi ti wọn n fẹ ṣe naa a ma mu ki wọn pe aarẹ ko wa wi tẹnu rẹ, ti o si ṣeeṣe ki wọn yọ nipo latari rẹ.

Ohun ti wọn n ṣe iwaadi le lori ni pe, Trump halẹ mọ orileede Ukrain pe ohun ko ni ṣe iranwọ nnkan ogun fun wọn ti wọn ko ba bẹrẹ iwaadi alatako rẹ kan to n ba du ipo.

Aarẹ Trump ni, ọwọ oun mọ, ati pe wọn fẹ fi iwadi naa dunkoko mọ oun ni; Sugbọn ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ Democrat, Nancy Pelosi ni o di dandan ki aarẹ Trump wa wi tẹnu rẹ

Kini o mu ki iwaadi yi ṣe pataki?

Pataki iwaadi yi ni pe, o ni ṣe pẹlu aarẹ Amẹrika ati alatako rẹ to n lewaju lara awọn to fẹ gba ijọba lọwọ Trump ninu idibo aarẹ ọdun 2020.

Awọn alatako Trump ni, niṣe lo n dun mọhurumọhuru mọ ileeṣẹ aarẹ Ukraine ki wọn ba le ba ṣe akoba alatako rẹ ninu ẹgbẹ Democrat, Joe Biden

Aworan Hunter Biden ati Baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Teresa Kroeger/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Hunter Biden n wo Baba rẹ Joe Biden, nibi to ti n ba awọn eeyan sọrọ layẹyẹ kan lọdun 2016

Ẹwẹ, ọgbẹni Trump ati awọn alatilẹyin rẹ naa n naka abuku si Biden to figba kan jẹ igbakeji aarẹ, pe o lo ipo rẹ lọna aitọ ki Ukraine ma ba ṣe iwaadi to le tu asiri pe ọmọ rẹ Hunter, ṣe aṣemaṣe.

Ọgbẹni Biden lo n lewaju lati di oludije ti wọn yoo gbe aṣia ẹgbẹ Democrat fun lati kopa ninu idibo aarẹ lọdun to n bọ.

Ni ṣoki, ọrọ yi niṣe pẹlu ẹni ti yoo di aarẹ ilẹ Amẹrika

Nibo ni ọrọ yi ti wọwa?

Aarẹ Trump ati aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky jijọ sọrọ lori ẹrọ alagbeka lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Keje ọdun yi.

Wọn fẹsun kan aarẹ Trump pe o mura mọ aarẹ Zelensky lati ṣe iwaadi igbakeji aarẹ ana, Biden to n ba du ipo.

Aworan aarẹ Volodymyr Zelenskynibi to ti n sọrọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ni ibẹrẹ ọdun yi ni Volodymyr Zelensky gun ori alefa gẹgẹ bi aarẹ Ukraine

Wọn ni o ṣeeṣe ki aarẹ Trump ti sọrọ nipa iranwọ òjìlénígba lé mewaa miliọnu dọla, nkan ija ogun ti ile asofin Amẹrika ti buwọlu, amọ ti ijọba Trump ko ti juwọ rẹ silẹ.

Iroyin sọ pe, aarẹ Trump paṣẹ fun adele olori oṣiṣẹ ile ijọba rẹ Mick Mulvaney, lati dawọ iranwọ naa duro titi di igba ti ohun yoo ba aarẹ Ukraine sọrọ tan lori ago.

Aarẹ Trump ni lootọ loun ba aarẹ Zelensky sọrọ nipa ọgbẹni Biden, ṣugbọn ohun ko dunkoko mọ pe ki o we ẹsun mọ alatako rẹ lẹsẹ

Njẹ aarẹ Trump ti fidi ọrọ yi mulẹ?

O jọ bẹ.

Ọgbẹni Trump ni oun ba ọgbẹni Zelensky sọrọ nipa ipenija ajẹbanu ati nipa ọgbẹni Biden ati ọmọ rẹ Hunter, to fi mọ awọn nkan miran.

O ni ọrọ naa jẹ eleyi to da lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ - ọrọ ti ko lẹjabakan ninu.

Crimea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ukraine ti ri ọpọ iranwọ gba lẹyin ti orileede Russia gba akoso iṣejọba Crimea lọdun 2014

Ki lawọn oloṣeeelu US miran n sọ?

Awọn ọmọ ile aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Democrat ni, ipe ori ago naa eleyi ti eeyan kan tu asiri rẹ ṣe pataki, nitori o tan imọlẹ si bi aarẹ Trump ṣe n ṣe pẹlu awọn olori orileede miran.

Awọn alatakọ sọ pe, ni ṣe ni aarẹ Trump mura mọ aarẹ Zelensky ki o ba le ṣe iwaadi ọmọ alatako rẹ, lọna ati ṣe akoba fun un.

Nancy Pelosi n wo aarẹ Donald Trump nigba ti o n ba ile aṣojuṣofin sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Abẹnugan ile to jẹ ọmọ ẹgbẹ Democrat, Nancy Pelosi lo lewaju iwaadi to fẹ daba ki wọn yọ aarẹ Trump

Njẹ aarẹ ṣe ohun ti ko tọ?

Ti ọrọ ba kan ẹsẹ ti wọn a fi yọ aarẹ nipo, orisirisi ni awọn ẹṣẹ naa, ti o si jẹ pe ohun ti ile ba panupọ pe o jẹ ẹsẹ aṣemaṣe naa ni wọn yoo fi yọ aarẹ nipo.

Ko daju pe awọn ọmọ ẹgbẹ Republican to jẹ ẹgbẹ Trump yoo dibo lati yọ aarẹ to jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn.

Ọrọ naa yoo gba oye, nitori ki wọn to le ri aarẹ yọ, pupọ ninu awọn aṣofin ni yoo tẹwọgba aba naa.

Boya wọn yoo ri Trump yọ tabi ko ni ri bẹ, ni ohun to ku ti awọn eeyan n tẹti leko le lori ọrọ to wa nilẹ yi.

Aworan aarẹ Bill Clinton ninu ọfisi aarẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bill Clinton ni aarẹ ikẹyin ti wọn buwọlu aba lati yọ nipo

Aarẹ meji ni awọn ọmọ ile aṣofin ti buwọlu aba pe ki wọn yọ nipo ninu itan Amẹrika.

Andrew Johnson jẹ ọkan ninu wọn lọdun 1868, ti ẹnikeji si jẹ Bill Clinton lọdun 1998.

Ko si kankan ninu wọn ti wọn ri aga yẹ nidi rẹ kuro nipo.

Akojọpọ iroyin tati ọwọ Anthony Zurcher a Tara McKelvey