Aarẹ Trump yọ Rex Tillerson kuro nipo

Rex Tillerson ni Chantilly, Virginia

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Tillerson lo ọdun kan pere lẹnu iṣẹ

Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump ti yọ minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson kuro loye bi ẹni nyọ jiga.

Lẹyẹ o sọka si ni o yan Mike Pompeo to jẹ ọgaagba ileeṣẹ alami ilẹ Amẹrika, CIA lati rọpo rẹ.

Aarẹ Trump dupẹ lọwọ ọgbẹni Tillerson fun iṣẹ rẹ lori opo ayelujara Twitter rẹ, o sọ pe akọwe titun yoo ṣe "iṣẹ ti o tayọ".

Aare Buhari ati Ọgbẹni Rex Tillerson ninu ipade naa

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Rex Tillerson n pada si America lojo isegun

Ọgbẹni Tillerson, ti o figbakan jẹ oludari ati alakoso ileeṣẹ ExxonMobil, wa ni ipo fun ọdun kan pere.

Aarẹ America naa tun yan Gina Haspel lati di alakoso obinrin akọkọ ọgaagba ileeṣẹ alami ilẹ Amẹrika (CIA).

Ọgbẹni Tillerson wa lori isinmi lẹyin abẹwo rẹ si ile Afirika nigbati ko ro wipe ọgbẹni Trump yoo yọ oun nipo, ati wipe Aarẹ Trump gba aba lati ṣe ijiroro pẹlu olori orilẹede North Korea, Kim Jong-un.

Aarẹ Buhari ni aarẹ ti Rex Tillerson ṣe ipade pọ pẹlu gẹgẹ bi aṣoju ati akọwe ijọba orilede America.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: