Awọn sẹnatọ Naijiria ni ootọ lawọn n gba miliọnu mẹtala abọ naira

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate
Ileegbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe ko si ohun tuntun kan ninu miliọnu mẹtala abọ naira ti ọkan ninu awọn asofin agba naa, sẹnatọ Shehu Sani kede laipẹ yii wi pe awọn n mu rele losoosu yatọ si owo osu wọn gan an ni san an.
Agbẹnusọ fun ile asofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnatọ Aliyu Sabi Abdullahi tun fi ẹyin ọwọ gba iroyin ti o nja ranyinranyin kaakiri wi pe awọn asofin agba yoku ti n kanra mọ Sẹnatọ Sani wi pe o tu asiri wọn faraalu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sẹnatọ Abdullahi ni ibasepe awọn araalu ti farabalẹ wo iwe eto isuna ile asofin naa ni, yoo ti han gbangba si wọn wi pe awọn owoona fun irinajo, itọju aisan ati bẹẹbẹẹlọ wa labẹ eto isuna ile naa, eyi si ni wọn pin fun awọn asofin naa.

Lati ọdọ: Ajọ to n pin owo ilu lorilẹ̀ede Naijiria, RMAFC, http://www.rmafc.gov.ng/

''Gbogbo awọn to di ipo oselu mu ni wọn ni owo ti wọn fi n se amojuto aaye wọn, ko si si ẹni ti yoo wa pe irufẹ owo bẹẹ ni owo osu wọn."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Sẹnatọ Shehu Sani ti o n soju ẹkun idibo apapọ kan ni ipinlẹ Kaduna tu ew lara ọrọ owo osu awọn asofin apapọ lorilẹede Naijiria nipa kikede rẹ wi pe yatọ si owo osu, ọkọọkan awọn asofin agba lorilẹede Naijiria lo n gba miliọnu mẹtala abọ losu.

Lati ọwọ iwe atigbadegba: Arabian Journal of Business and Management Review (OMAN Chapter)Vol. 5, No.5; December 2015.

Eyi ti fa ọpọlọpọ awuyewuye laarin awujọ orilẹede Naijiria, paapaajulọ pẹlu bi iroyin se ti nkaakiri ilu saaju asiko yii wi pe awọn asofin Naijiria lo n gba owo to pọ julọ laarin awọn akẹgbẹ wọn lagbaye.












