Trump: FBI ko mọ isẹ wọn bi isẹ

Ọmọbirin kan joko ti agbelebu iranti kan ni Parkland, ni ipinlẹ Florida.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikọlu ile-iwe kan ni ọjọru l'agbegbe Parkland ni eleyi to buru ju l'Amerika lati ọdun 2012

Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump ti bu ẹnu atẹ lu ileese agbofinrọ orilẹede naa (FBI) nitori wipe ileese naa kuna lati dẹkun iyinbọn paniyan to waye ni ile iwe ipinlẹ Florida.

Trump ni kaka ki FBI se eleyi, ileesẹ naa kan fi akọkọ s'ofo ni lori wiwa ẹri ti yoo fi han wipe Russia padi apo pọ pẹlu ẹto ipolongo - idigbọ oun.

O sọ wipe: "Ko si ipadi-apo-pọ kankan. Ẹ pada s'ori ise, kẹ si fun gbogbo wa l'oriyin."

Ileesẹ FBI ti gba wipe o kuna lati gbẹ igbẹsẹ kankan lori olobo ti wọn taa nipa afurasi Nikolas Cruz to yibọn pa awọn eniyan.

Ọgbẹni Cruz ti jẹwọ wipe oun lo yin ibọn pa eeyan mẹtadinlogun ni agbegbe Parkland to wa ni ipinlẹ Florida.

Iyinbọn paniyan naa lo jẹ ẹlẹyi to buru ju l'Amerika lati ọdun 2012 o si ti n fa ariyanjiyan lori fif'ofin de ibọn rira.