Yoruba Language: Ṣé ẹ mọ ìdí tí ọmọ fi ń jẹ́ orúkọ yìí?
Lẹyin Taye, Kehinde, Idowu, Alaba, o ni orukọ amutọrunwa pataki ti Yoruba a maa sọ ọmọ to ba tun waye lẹyin awọn wọnyii.
BBC Yoruba pẹlu akanṣe eto gbigbe ede Yoruba larugẹ mu ibeere naa tọ awọn ọmọ Yoruba atata lọ boya mimọ ede wọn daju ṣi n ṣiṣẹ wara wara lori wọn.
Idogbe ati Idoha lawon to tun tẹle Ibeji, Oyilaki, Ọba ọmọ,ti Yoruba gba pe wọn fẹsẹ meji bẹ kẹsẹ sile alakisa, ti wọn ọ alakisa donigba aṣọ.