Ọmọ Yoruba di ẹni akọkọ to kawe f'ọgọfa wakati

Oríṣun àwòrán, Twitter/@iread_bayode
Ọmọ Naijiria kan, Bayọde Treasure Ọlawunmi ti di ẹni akọkọ to kawe sọke fun ọgọfa wakati lai simi ju wakati meji lọ nijọ kọkan laarin ọjọ maarun.
Bayọde di ẹni akọkọ ti yoo ṣe iru ẹyi ni ileikawe YouRead to wa ni Yaba, l'Eko lago mẹta-abọ lọjọ Abameta.
Asiko to lo to fi kawe soke lera-lera ju ti ẹni to wa nipọ yii telẹ, Deepak Sharma, ọmọ orilẹede Nepal, lọ.
Bayọde, to kawe fun nnkan bi wakati mejilelọgọfa, o si simi fun wakati meji-meji ninu wakati mẹrinlelogun kọkan.
O ni oun ṣe bẹ ni lati pakiesi awọn eeyan si aṣa iwe kika ati iwe kikọ ni Naijiria.








