Marosẹ Ibadan si Eko: Fashola sọ pe asepati rẹ yoo se akoba ọrọ aje

Opopona Ibadan silu Eko

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ijọba gbọdọ pese owo to towo lati s'atunse marosẹ Ibadan silu Eko

Igbimọ ile asoju-sofin ilẹ wa to wa f'ọrọ isẹ ode, eyiti Asofin Toby Okechukwu ko sodi, gbalejo minisita fun ohun amusagbara, isẹ ode ati ilegbe, Babatunde Fasọla lana, ẹni to wa sọ okodoro ọrọ nipa ohun to rọ mọ isẹ atunse opopona marosẹ Ibadan silu Eko ati igbesẹ kikọ afara Niger keji.

Nibi ipade naa si ni Fasọla ti la ọrọ mọlẹ pe ayafi ti ijọba ba pese owona toto lati gbọ bukata atunse opopona marosẹ Ibadan silu Eko nikan ni ọna abayọ lati pari isẹ naa nitori ọgbọn ko di igi, afi okun nikan.

Fasọla ni bakanaa l'ọmọ sori pẹlu isẹ kikọ afara Niger keji, to si n para poro pe awọn isẹ akanse mejeeji yi se pataki pupọ, ti a ko si gbọdọ fi akoko sofo nipa diduro de eto iduna-dura ọlọjọ pipẹ to maa n waye lasikoigbesẹ idokowo laarin ijọba ati ẹka aladani gẹgẹbi ọna min lati pese owona fun isẹ naa,pẹlu afikun pe ilana idokowo laarin ijọba ati ẹka aladan toun jogun lasiko toun gba ipo minisita ko ni oore kankan ti yoo se fun ilẹ wa.

Fasọla bẹbẹ fun atilẹyin awọn asoju-sofin lori atunse marosẹ Ibadan si Eko

Babatunde Fasọla n bawọn asoju-sofin jiroro pọ

Oríṣun àwòrán, Fasola/twitter

Àkọlé àwòrán, Ijọba nilo atilẹyin awọn asofin lori atunse marosẹ Ibadan silu Eko

O wa rawọ ẹbẹ sawọn asofin naa pe, taa ba fẹ gbọ bukata isẹ akanse mejeeji yi, igbọraẹniye ati atilẹyin gbọdọ wa lati ẹka asofin, to si n fi ewe ọmọ mọ awọn asofin naa leti pe ijafara lewu o, nitori taa ba jẹ ki asepari isẹ atunse opopona marosẹ Ibadan silu Eko maa fa nilẹ bii igbin, eyi lee lewu pupọ lori ọrọ aje ilẹ Naijiria, ti ọrọ aje wa yoo si bẹrẹ si ni mọ asepati isẹ naa lara laipẹ.

Nigba ti wọn n da si ijiroro yi, asofin meji, Pattegi Ahman ati Muhammed Bago fọwọ sọya pe awọn faramọ pe ki ijọba se afikun owo to ya sọtọ fun atunse marosẹ Ibadan si Eko, wọn ni, tijọba ko ba se bẹẹ, yoo gba ilẹ wa to ọdun mẹjs ko to lee pari opopona marosẹ naa.

Amin iyasọtọ kan
Babatunde Fasọla

Oríṣun àwòrán, Fasola/Twitter

Àkọlé àwòrán, Akoba yoo ba ọrọ aje Naijiria ti a ko ba tete se atunse marosẹ Ibadan silu Eko.

Awọn koko ọrọ min ti Fasọla tun sọ nile asofin:

  • Ilana idokowo laarin ijọba ati ẹka adani to wa nilẹ lat'ọdun 2015 ko muna doko.
  • Aroye ati ọrọ ileejọ ti pọ ju lori awọn isẹ to wa laarin ijọba ati ẹka adani.
  • Awọn agbasẹse nilẹ Naijiria ko ni owo to towo lati gbọ bukata akanse isẹ to lowura bii atunse opopona marosẹ Ibadan si Eko.
  • Biliọnu mọkanlelọgbọn naira ti wọn ya sọtọ fun isẹ yi ni 2015 ko ba gbọ gbogbo bukata atunse opopona naa.
  • Biliọnu marun o le diẹ ni yoo pari afara Niger kejiI
  • Ijọba Ọbasanjọ lo fi tipa-tipa gbe ilana idokowopọ laarin ijọba ati ẹka adani le awọn ọmọ Naijiria lori.
Amin iyasọtọ kan