Visa Application: Amẹ́ríkà ń béèrè ìròyìn ojú òpó arìnrìnàjò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo awọn eeyan to ba fẹ rinrin ajo lọ sorilẹede Amẹrika bayii gbọdọ ṣetan ati ko gbogbo iroyin to ba jọ mọ iṣe wọn lori ayelujara kalẹ.
Eyi fihan pe gbogbo iroyin to ba jọ mọ Facebook, Twitter ni awọn to n wa iwe aṣẹ irinna sorilẹede Amẹrika bayii gbọdọ ṣetan ati fa le awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ilẹ Amẹrika lọwọ lasiko eto naa.
Eyi ri bẹẹ nitori pe bayii, orilẹede Amẹrika ti ni lara awọn ohun amuyẹ ti oun yoo maa beere lọwọ awọn to ba fẹ gba iwe aṣẹ irinna silẹ okeere ni iroyin nipa oju opo wọn lori ikanni ayelujara Facebook, twitter atawọn miran. Ko din ni miliọnu mẹrinla awọn arinrinajo lọdun to fi mọ awọn atipo to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin ti aṣẹ yii lee kan.
Ni oṣu kẹta ọdun 2019 ni ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere ni ilẹ Amẹrika kọkọ kede igbesẹ tuntun yii lẹyin aṣẹ aarẹ orilẹede naa, Donald Trump pe ki wọn tubọ san okun ayẹwo fawọn arinrinajo si orilẹede naa ko gbopọn sii.
Ṣaaju aṣẹ tuntun yii, awọn arinrinajo ti wọn ba fura si nikan ni wọn maa n beere iroyin nipa oju opo ayelujara lọwọ wọn, papaa awọn to ba ti rinrinajo lọ sawọn orilẹede to ni ajọṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ agbesumọmi.








