Islamic New Year: Ọdún mùsùlùmí Hijiri tuntun bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Bi awọn musulumi ni Naijiria ṣe n ki ara wọn ku orire ibẹrẹ ọdun tuntun wọn, igbimọ alakoso ẹsin Islam ni Naijiria, NSCIA ti sọ pe, ọjọ Jimọ, ọjọ Kọkanlelogun oṣu Kẹjọ ni onka ọdun tuntun yoo bẹrẹ.
Wọn ni idi ni pe awọn ko ri oṣu Muharram, ti o n tọka pe oṣu naa ti bẹrẹ.
Ikede yii wa loju opo ajọ NSCIA to wa ni Facebook ti wọn fi sita lorukọ Sultan Sokoto, tii ṣe olori awọn musulumi Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Háà, èyí tún ga! Wó ọkùnrin táwọn obìnrin fipá bá lòpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì
- Bí ìyàwó rẹ bá lóyún tàbí bímọ ní ìpínlẹ̀ Oyo, wo bí o ti ṣe lé gba ìsinmi ìtọ́mọ (Paternity leave)
- Ẹ̀bùn #500,000 wà fún ẹni tọ bá ba wa rí afurasí ikú Akinyẹle tó sọnù- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Wo àmúyẹ kí o tó lè di ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú fọ́ọ́mù tó jáde yìí
- Ṣé òótọ́ ni pé ìgbẹ́ erin le è wo arùn Coronavirus sàn?
- Wo ìdí tí Osun fi kede ìsinmi fún ọdún ìṣẹ̀ṣe, tàwọn ìpínlẹ̀ yókù kò dáhùn,
Ṣugbọn o, ọpọ eeyan ni ko mọ wi pe awọn larubawa ti n ṣe amulo ọdun oloṣu mejila naa, ṣaaju ki Anọbi Muhammad (SAW) to daye.
Oṣu oju ọrun yii ti wa tipẹ ti awọn musulumi si mu lo, lẹyin igba ti Anọbi rinrin ajo lati Makkah lọ si Madinah.
AH, ti wọn n kọ sẹyin ọdun yii tun mọ si lẹyin igba Hijrah.
Nitori pe oṣu oju ọrun ni wọn maa n tẹle, ko si kankan ninu awọn oṣu yii ta le sọ pe gerege iye ọjọ bayii lo jẹ.
Lọpọ igba, iyatọ ọjọ mọkanla a maa waye laarin ọdun kan si omiran, bakan naa, iye ọjọ oṣu kọọkan le yatọ si ara wọn.
Bi oṣu mii ba pe mọkandinlọgbọn, omiran le pe ọgbọn tabi ki o si jẹ mejidinlọgbọn.
Alaye ree lori orukọ awọn oṣu kọọkan itumọ ati bi wọn ṣe n pe wọn:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Muharram:
Osu yi tumọ si oṣu eewọ lede larubawa.
Ohun ni osu kini ọdun musulumi, tawọn musulumi si ma n yago fun ogun jija, itajẹsilẹ tabi itahun sira ẹni ninu oṣu yii.
Safar:
Oṣu keji ọdun ree, o tumọ si ifayegba, nitori oṣu yii lawọn larubawa maa n ṣe ikọlu sawọn ilu to ba wa lagbegbe wọn laye atijọ.
Rabi-Al Awwal:
Oṣu Kẹta ree, ohun si ni igba ti irugbin maa n ṣu yọ, to si ṣe deede pẹlu asiko ti irugbin maa n gberi lọdọ wa nibi.
Rabi-Al Akhir:
Oṣu yi tumọ si ipari asiko tiirugbin maa n ṣu yọ.Wọn a tun maa pe oṣu yi ni Rabi Al Thani.
Jumada- Al Ula:
Orukọ oṣu yi waye latari bi ọgbẹlẹ ṣe maa n waye .Awọn kan sọ pe wọn fi asiko ti ọgbẹlẹ maa n waye fi sọri oṣu yi.
6 Jumada Al Akhirah- Idakeji oṣu Jumada-Al Ula ni oṣu yi jẹ.Ohun ni asiko ti ọgbẹlẹ ba wa si opin.

Oríṣun àwòrán, @Aquabi
Rajab:
Oṣu ọwọ ati eewọ ni oṣu yi jẹ.Awọn larubawa kii jagun loṣu yi rara ati rara
Sha'aban:
Oṣu Kẹjọ ni Sha'aban.Ninu oṣu yi lawọn larubawa maa n fọnka lori lẹ lati wa omi ati ounjẹ fun nnkan ọsin wọn.
Ramadan:
Ramadan tumọ si asiko ti nkan ba gbona. Ninu oṣu yii to gbajumọ ju, lawọn musulumi maa n gbawẹ ọlọdọọdun.
Asiko yii loju ọjọ maa n gbona ju lọdọ awọn agbegbe larubawa.

Shawwal:
Orukọ oṣu yi wa latari bi awọn rankumi ṣe maa n ru ju ti tẹlẹ lọ ti omi mu wọn a si ma kere ju ti tẹlẹ lọ.
Dhul Qiddah:
Ninu oṣu yi lawọn larubawa maa n ṣe adehun lati dẹkun ija jija.Wọn kii jagun tabi ba ara wn ja loṣu yi.
Dhul Hijjah:
Ninu oṣu yi lawọn musulumi maa n ṣe irinajo Hajji lọdọọdun.O wa lara awọn oṣu to gbajumọ laarin awọn larubawa.













