Ramadan: Àwọn ọlọ́pàá Sharia tí ń mú aṣéwó àti ọ̀daràn nípínlẹ̀ Kano

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
Àwọn ọlọ́pàá Sharia tí mú àwọn ènìyàn to lé ni ààdọta ti wọn funra si gẹ́gẹ́ bi aṣẹwó àti ọdaran lójúnà àti mú àdínku bá ìwá ẹsẹ̀ lásiko ààwẹ ramadani tó ń bọ̀.
Agbẹnusọ Hisbah tí a mọ si ọlọpaa Sharia Adamu Yahaya sàlàyé fún BBC pé ìgbésẹ̀ náà jẹ òhun ti wọn máa ń ṣe ni gbogbo ìgbà gẹ́gẹ́ bi imúrasilẹ̀ de osù ramadani pàápàá jùlọ àwọn agbegbe ti àwọn ǹkan burúkú ti máa ń ṣẹlẹ̀ láti lé ri pé àwọn ènìyàn Kano gbé aradi dé ààwẹ.
"Lọ́dọọdún kí ààwẹ ramadan tó dé ni à máa àkanṣe jákejádo láti mú àwọn tó ń hu ìwà ti kò bójú mu nílana ẹsin wa. Àsìkò ààwẹ jẹ àsikò ti ó dára jùlọ ni àyíká yìí a si fẹ ki àwọn ènìyàn sín ọlọrun kíkó irú àwọn ènìyàn báyìí kúro ilẹ yóò mú ki àwọn ara ilú le pa ọkan wọn pọ si ojú kan láti lé ṣe iṣẹ́ ẹsin fún Ọlọrun."
Ó ku ọ̀sẹ̀ kan gbáko ló kùn ti gbogbo Musulumi lágbaye yóò bẹ̀rẹ̀ ààwẹ ọlọgbọ̀n ọjọ ti a mọ si oṣu ramadan.

Oríṣun àwòrán, kano
Ipínlẹ̀ Kano jẹ ọkan nínú àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà to ń lo ofin Sharia ti Hasbah si dúro gẹ́gẹ́ bii ọlọpàá ẹsin fún ipinlẹ̀ náà.
Yahaya fí kún pé ti àwọn ba wa mú ẹnikẹni to si lé mú àrídaju jáde pe òun kìí ṣe aṣẹ́wó tàbí ọ̀daràn, àwọn ó dáa silẹ̀ láti maa lọ.
"À ń bá àwọn onímọ ṣiṣẹ. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà à ní àwọn ọtẹlẹ̀múyẹ ní àwọn bi a ti lọ ń ko àwọn aṣẹ́wó tàbi ọdaran. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ǹkan ti à ń ṣe máa ń jẹ òòtọ sùgban ti a ba mú wọn tán ti wọn si ni ẹ̀rí máa jẹ mi nìsó à ó fi ẹni náà silẹ̀ nígba ti àwọn ti igbá ba ṣímọ lóri yóò fi ojú ba ile éjọ









