Kidnap cases in Nigeria: Iléeṣẹ́ ọ̀lọ́pàá ní ọwọ́ tẹ afurasí méjì, méjì míì sálọ

Obinrin kan ti wọn mu ni igbekun

Oríṣun àwòrán, Others

Ọwọ sinkun ọlọpa nipinlẹ Oyo ti ba ọkunrin meji lori ẹsun pe wọn ji obinrin onisowo nla kan gbe pamọ.

Awọn afurasi ajinigbe naa, Abubakar Muhammed ati Ayankunle Ayanleye nileesẹ ọlọpa tun fi ẹsun ipaniyan kan pẹlu, ọjọ kewa osu keje ọdun 2020 si ni isẹlẹ naa waye.

Awọn mejeeji naa, lasiko ti wọn fẹ ji obinrin onisowo ọhun, Modupeoluwa Oyetoso gbe salọ, tun ni wọn yinbọn pa afẹsọna rẹ, Opeoluwa Oladipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ilu Lanlate nijọba ibilẹ Ibarapa nipinlẹ Oyo si ni isẹlẹ naa ti waye.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi salaye pe ẹrọ ilewọ Tecno kan ati ibọn lawọn afurasi lo.

Àkọlé fídíò, Rape cases in Nigeria: Ọmọ ọdun 5 àti 14 ni Kalu wà nígbà tí obìnrin fipá ba lòpọ̀

Bakan naa lo ni wọn ba ẹgbẹrun lọna mejilelogun ati aabọ lọwọ wọn, owo naa si wa lara owo itusilẹ ti wọn gba lori onisowo naa ti wọn ji gbe.

Fadeyi ni ileesẹ ọlọpa tun ti n saayan lati se awari awọn afurasi meji mii to mọ nipa isẹlẹ naa, amọ ti wọn ti juba ehoro.

Obinrin onisowo naa ati afẹsọna rẹ ni wọn wa ninu ọkọ Toyota Highlander lasiko ti wọn ji obinrin naa gbe.

Awọn mejeeji si n ti inu oko wọn bọ ni lasiko tawọn afurasi mẹrẹẹrin naa da wọn lọna ni deede aago marun irọlẹ.

Baale Apese d'àwátì, ó bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé!

Ade Yoruba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ade Yoruba

Ikede ti jade wi pe wọn ti ji Oloye Razak Olaseinde Adamson to jẹ Baalẹ ilu Apese ni ijọba ibilẹ Eti Osa, ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi awọn mọlẹbi rẹ ṣe sọ ọ, lati ọjọ iṣẹgun ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹrin lo ti di awati laafin nigba tawọn kan ba a lalejo.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Mọlẹbi rẹ kan ni lẹyin ti Baalẹ gba ipe latọdọ awọn kan ti wọn ni awọn n bọ wa saafin rẹ to si lọ pade wọn ni ko ti pada saafin lati igba naa.

"Wọn gba ipe lori ẹrọ alagbeka rẹ wọn si ṣalaye ọna de aafin fun awọn kan. Nigba to gba ipe naa tan, o ni oun n lọ ba wọn ṣugbọn arimọ wọn la ri o!".

"A ti gbiyanju lati pe wọn titi lori ẹrọ alagbeka ṣugbọn pabo lo n ja si".

O ti le lọjọ marun bayii ti Baalẹ Razak ti di awati. Awọn mọlẹbi rẹ ni awọn ti lọ fi ọrọ naa lọ ni agọ ọlọpaa Ajiwe to wa ni Ajah ṣugbọn awọn ko tii ri ipa koko kankan niwọn igba ti ọwọ ko tii tẹ awọn ajinigbe ọhun.

Ẹwẹ, iroyin s pe ọlọpaa kan lati agọ Ajiwe ti ko fẹ fi oju han sọ pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi kọọkan ti iwadii si ti n lọ lọwọ lati igba ti wọn ti wa fi ọrọ naa to wọn leti.