Game of Thrones vs Ìrèké Oníbùdó: Ǹjẹ́ ìfarapẹ́ra wà nínú fíìmù méjèèjì?

Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Ọpọlọpọ awọn eniyan lo kundun ere agbelewo ‘Game of Thrones’ to sọ nipa igbe aye ala ti ko le sẹ ‘Fantasy World’awọn eniyan ilẹ Westeros ati agbeegbe Essos lori bi wọn se n gba ijọba kan si omiiran, ti o si kun fun awọn abami eniyan.
Ọdun 2011 ti wọn bẹrẹ fiimu ‘Game of Thrones’ ni ori ẹrọ ikansiraẹni lori ayelujara ti n sọ kutukutu wọwọ, eleyii ti wọn yoo si pari ni ọdun 2019.
Amọ, Ireke Onibudo to jẹ iwe kika Yoruba, ni wọn fi se fiimu ni ọdun 2009, sọ nipa itan igbesi aye ọkunrin akinkanju ati bi o ṣe kuro nipo alaini di ọba. awọn eroja to wa ninu fiimu mejeeji lo jẹ ki a wo ifarajọra to wa ninu wọn.

Kini ajọsepọ to wa laaarin ‘Game of Thrones‘ ati ‘Ireke Onibudo’?
- Game of Thrones ati Ireke Onibudo jẹ adakọ iwe. Inu iwe ‘A song of Ice and Fire’ ti George Martins kọ ni wọn ti se fiimu yii bẹẹ naa si ni wọn da iwe Ireke Onibudo ṣe si sinima agbelewo eyi ti Tunde Alabi dari ẹ.
- Ninu iwe Ireke Onibudo, Ireke to kọ ipa ribiribi ninu fiimu naa ba ọpọlọpọ abamiẹda ja bii Ewure iberù. Bakan naa ni Jon Snow ninu fiimu ‘Game of Thrones’ naa ba awọn abamiẹda ẹranko ja bii ‘Dragon’.
- Bi o tile se pe ọpọlọpọ lo n sọrọ nipa fiimu Game of Thrones, ti eniyan to ju miliọnu mẹtadinlogun tilẹ wo ‘season 8’ lọjọ ti fiimu naa kan oju opo ayelura. Amọ, awọn ẹya Yoruba lo gba iwe Ireke Onibudo bii igba ọtin, ti o si pọn dandan fun ẹnikẹni to ba ko Ede Yoruba.
- Ninu fiimu mejeeji awọn ogbontagiri wọn ja ogun lọpọlọpọ lati bori gbogbo isoro to koju wọn ki o to di wi pe wọn yoo de ilẹ ileri.
- Bi o tilẹ jepe ‘Game of Thrones’ se afihan ihoho awọn eniyan, Ireke Onibudo se igbelarugẹ bibo ihoho ẹda ati igbeyawo laarin iyawo kan ati ọkọ kan.









