JAMB: Ìgbésẹ̀ ti ń lọ lórí èsì ṣùgbọ́n kò tíì sí gbèdéke ọjọ́ tí yóò jáde

JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Àkọlé àwòrán, Àjọ JAMB ní àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ tó lé ní mílíọ́nù kan tó kópa nínú ìdánwò JAMB tó wáyé ní Osù Kẹ́rin, ọdún 2019.

Ajọ JAMB ni ko tii si gbedeke fun ọjọ ti esi idanwo aṣewọle si ileewe giga UTME lọọkan.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC news Yoruba, alukoro fun ajọ JAMB, Ọjọgbọn Benjamin Fabian ṣalaye pe, loots ni ajọ naa ti bẹẹrẹ gbogbo igbesẹ ti o yẹ ko ṣaaju ijade awọn esi idanwo awọn akẹkọ naa ṣugbọn ko tii lee sọ ni pato ọjọ ti esi naa yoo jade.

Ọjọgbọn Fabian tun fi kun un pe lasiko ti esi yii ba jade, gbangba laṣa ta ni wọn yoo fi ṣe ati pe gbogbo akẹkọ toi ṣe idanwo naa ni wọn ti fi ọna ti wọn yoo gba ri esi wọn ṣọwọ si.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Benjamin tun kilọ fun awọn to se idanwo JAMB lati ri wi pe wọn sọ nọmba ti wọn fi se iforukọsilẹ, ki awọn onijibiti ma ba a lu wọn ni jibiti.

O fikun wi pe awọn onijibiti naa le e mu nọmba ẹrọ ilewọ wọn lati fi gba owo lọwọ wọn pẹlu adehun pe wọn yoo fun wọn ni esi idanwo to dara ninu idanwo JAMB.

Ajọ JAMB naa wa parọwa si awọn lati ri wi pe wọn tọju awọn ohun to se pataki si esi idanwo wọn bii nọmba ti wọn fi se iforukọsilẹ.