Bayelsa Lawmakers: Tí o ba buwọlu owo ìfẹyìnti yòó di ọ̀rọ̀ ile ẹjọ - SERAP

Seriake Dickson

Oríṣun àwòrán, Dicksonofficial

Àkọlé àwòrán, Ajọ náà fi kún pé ti wọn ba fi le buwólu abadofin, owó ìfẹyin ti láílái yìí, ó túmọ si pe, ilé ìgbìmọ àsofin náà ti tàpá si òfin Nàijíría àti ti àgbáye.

Àjọ SERAP tí gba gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa Seriake Dickson ní ìmọràn láti máa buwọlu àbádofin gbigba owó ìfẹ̀yìnti láíláí ti àwọn ilé ìgbìmọ asòfin ìpínlẹ̀ náà gbé si ìwáju rẹ̀.

Nínú lẹ́tà ti wọn kọ ránsẹ si gómìnà, ìgbákeji olùdarí SERAP Kolawole Oluwadare sàlàyé pé àbádofin ọ̀hún jẹ àṣìlò ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ àṣofin.

Àkọlé fídíò, Àwọn òbí mi rò pé ẹ̀jẹ́ ti ta sí ọpọlọ mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ba ẹranko igbó ṣọ̀rẹ́

"Àbádofin ọ̀hún kìí ṣe èyí tó tọ̀nà, ó si tún jẹ ṣíṣe àṣojú ará ìlú lọ́nà ti kò tọ, àti pé àṣìlò ìpò gbáà ni."

Gẹ́gẹ́ bi Kolawole Oluwadarfe ṣe sọ, ó ní kàkà kí wọn gbé àbádòfin ti yóò ṣe àwọn ọmọ láǹfàní ni ti ètò ẹkọ́ to yantranti ni Bayelsa, àwọn ọmọ ilé aṣofin ló ìpò náà fúb ànfani àrà wọn láti maa gba owó gọbọi léyin ti wọn ba kúrò nipò.

Ajọ náà fi kún pé ti wọn ba fi le buwólu abadofin, owó ìfẹyin ti láílái yìí, ó túmọ si pe, ilé ìgbìmọ àsofin náà ti tàpá si òfin Nàijíría àti ti àgbáye.

Tí ẹ ò bá gbàgbé, ni ọ̀ṣẹ̀ tó kọja ni àwọn ile ìgbìmọ asofin Bayelsa gbé àbádofin owó ìfẹyinti kálẹ̀ fún àbẹnugan ilé, igbákeji rẹ̀ àti àwọn ọmọ ilé tókù.

Nínú àbádofin náà àbẹnugan ile to fẹ̀yìnti yóò maa gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà lósù, nígbà ti ìgbákeji rẹ̀ yòó maa gba ẹgbẹ̀rún lánà agba ti gbogbo ọmọ ilé tokù yóò si máa gba ẹgbẹ́rùn lọ́nà ọgọ́run kan náírà.

Àwọn ọmọ ilé àṣofin náà fẹ maa gba owo ìfẹyinti bii ti ààrẹ orilẹ̀-èdè àti igbákeji wọn, àwọn ggomina àti igbakeji wọn jákejado orilẹ̀ èdè Naàìjíríà.

SERAP ní nínú ìwòyè àwọn ọ̀ps àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ àssofin ni yóò jẹ ànfani ọ̀hun ti yóò si máá ná ìpínlẹ̀ náà ni ogún miliọnu náírà lósoosu.