Sáà Premier League tuntun bẹ̀rẹ̀ lónìí, ẹ wo àwọn òfin tuntun tó bá dé

Aworan Mohamed Salah, Bukayo Saka, Erlin Haaland ati Cole Palmer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Idije Premier League ti saa 2025/2026 bẹrẹ lonii lẹyin ti saa bọọlu 2024/2025 pari loṣu Karun un to kọja.

Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool to gbafe ẹyẹ saa to lọ ni yoo ṣide saa Premier League 2025/2026 tuntun yii nigba ti wọn yoo maa koju Bournemouth lalẹ oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni papa iṣere Anfield.

Ọpọ awọn ololufẹ Premier League ni Naijiria ati kaakiri agbaye lo ti n foju sọna fun saa Premier League tuntun lati gberasọ.

Idije liigi tuntun yii yoo tun gbinaya lopin ọsẹ nigba ti Manchester United yoo maa gbalejo ikọ agbabọọlu Arsenal ni papa iṣere Old Trafford.

Wọnyii ni akojọpọ awọn ofin tuntun to ba idije Premier League saa yii de:

Awọn ofin tuntun to ba Premier League de fun saa bọọlu 2025/2026 tuntun

Omi tuntun ti ru ẹja tuntun si ti wọ ninu idije Premier League, ni saa bọọlu tuntun yii, aṣọle ko gbọdọ fi akoko ṣofo ti bọọlu ba wa lọwọ rẹ, bi bẹẹ kọọ, rẹfiri yoo paṣẹ pe ki ẹgbẹ bọọlu alatako gba kọna gẹgẹ bii ijiya fun aṣọle naa.

Wọn ṣe agbekalẹ ofin yii lati dẹkun bawọn agbabọọlu ṣe maa n fi akoko ṣofo.

Ofin to wa tẹlẹ ni pe aṣọle ko gbọdọ wa lori bọọlu ju iṣẹju aaya mẹfa lọ, ijiya si ni pe ẹgbẹ agbabọọlu alatako yoo gba fiiri-kiiki.

Amọ, ni saa bọọlu yii, aṣọle ko gbọdọ lo ju iṣẹju-aya mẹjọ lọ pẹlu bọọlu, bi bẹẹ kọọ, ẹgbẹ agbabọọlu alatako yoo gba kọna gẹgẹ bii ijiya fun aṣemaṣe gooli naa.

Wọn ti bẹrẹ si ni ṣe amulo ofin yii kaakiri ibi ti wọn ti n gba bọọlu, koda, wọn lo o ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn ikọ agbabọọlu FIFA Club World Cup ti Chelsea gba lorilẹede Amẹrika.

Ofin tuntun mii ni pe awọn Balogun ẹgbẹ agbabọọlu ni Premier League yoo lanfaani lati ba rẹfiri sọrọ ni saa bọọlu tuntun yii.

Bakan naa, rẹfiri le fun agbabọọlu to ba lọ ba a sọrọ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ n lọ lọwọ lai gbaṣẹ ni kaadi yẹlo gẹgẹ bi ikilọ.

Ko tan sibẹ o, agbabọọlu to ba tabuku rẹfiri nigba ti ere bọọlu n lọ lọwọ naa yoo gba kaadi yẹlo fun ikilọ.

Rẹfiri yoo maa faye gba agbabọọlu ti ẹsẹ rẹ ba ṣeesi kan bọọlu lẹẹmeji nigba to fẹ gba pẹnariti lati tun un gba

Lara awọn ofin tuntun ninu idije Premier League ti saa yii ni pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu lanfaani lati yan agbabọọlu mii gẹge bii Balogun ki ifẹsẹwọnsẹ to berẹ to ba jẹ pe goli ni Balogun ẹgbẹ agbabọọlu wọn.

Ofin tuntun miran ni pe rẹfiri yoo maa faye gba agbabọọlu ti ẹsẹ rẹ ba ṣeesi kan bọọlu lẹẹmeji nigba ti o fẹ gba pẹnariti lati tun un gba lẹẹkeji.

Amọ, bọọlu gbọdọ wọ inu awọn nigba to kọkọ gba pẹnariti naa.

Wọn ti lo ofin yii ninu idije EURO 2025 awọn obinrin nilẹ Yuroopu nibi pẹnariti ti waye laarin Spain ati England ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije naa eyi tawọn obinrin England ti jawe olubori.

Ti ẹ o ba gbagbe, agbabọọlu obinrin fun England, Beth Mead, yọ nigba to fẹ gba pẹnariti, ẹsẹ rẹ si kan bọọlu lẹẹmeji.

Bo tilẹ jẹ pe bọọlu naa wọle sawọn, Mead tun pẹnariti naa gba, amọ ọwọ goli Spain, Cata Coll lo gba a si.

Labẹ ofin ti tẹlẹ, rẹfiri ko ni jẹ ki Mead tun pẹnariti naa gba fun igba keji rara.

Ifẹsẹwọnsẹ saa Premier League tuntun ti yoo waye lọjọ Satide 16-08-25

Aston Villa v Newcastle United

Brighton v Fulham

Sunderland v West Ham United

Tottenham v Hotspur v Burnley

Wolves v Manchester City

Ifẹsẹwọnsẹ saa Premier League tuntun ti yoo waye lọjọ Aiku 17-08-25

Chelsea v Crystal Palace

Nottingham Forest v Brentford

Manchester United v Arsenal