FIBAN: Ìpàdé àláàfíà wáyé láàrin KWAM 1 àti FIBAN, ìjà pari

Kwam 1: Ọmọṣẹ Wasiu ni MC Murphy, to ba fẹ́ lọ sílé ẹjọ kó nìsó níbẹ̀- Alákòso orín K1

Gbonmi si omi o to to waye laarin ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ Naijiria ta mọ si FIBAN ati akọrin Fuji KWAM 1 ti pari.

Ọrọ naa yanju lẹyin ipade alaafia kan to waye tawọn mejeeji si ni awọn ti pana ohunkohun to n da wahala silẹ.

Ni aafin Olu ti ilu Itori ni ipade yi ti waye ti Wasiu Ayinde si sọ pe oun ko paṣẹ ki awọn ọmọ gbẹ oun kankan lu Mc Murphy.

Nitori naa aarẹ ẹgbẹ FIBAN Desmond Nwachukwu ti wa pasẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa jeburẹ ki wọn si bẹrẹ si ni lo orin KWAM 1 lori eto wọn.

Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Instagran/kingwasiuayindemarshal

'Nítori ààbò ẹmí MC Murphy ló fi gbá #100,000 lọ́wọ́ K1 lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀'

FIBAN vs Kwam 1: Nítori ààbò ẹmí MC Murphy ló fi gbá #100,000 lọ́wọ́ K1 lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ -FIBAN

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ FIBAN ti fi ààké kọrí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ to wáyé láàrin MC Murphy tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ wọ́n ní ìpińlẹ̀ Ogun àti gbájúgbaja olórín fújì, King Wasiu Ayinde Mashall.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀, ní ààrẹ ẹgbẹ́ FIBAN Desmond Nwachukwu sàlàyé pé, àwọn ṣì ń dúró de Ọjọ́rú ọjọ keje, ọdún yìí kí àwọn tó gbé ìgbẹ́sẹ̀ tó kan lórí ọ̀rọ̀ náà.

Nwachukwu ní, lẹ́yin ọjọ́ náà, ti Wasiu Ayinde ko ba bẹ̀bẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn ṣe kọ̀wé ránṣẹ́ sí í lórí ǹkan ti àwọn ń fẹ́ kó ṣe, lawọn yoo ṣe iwọde lọ sọdọ Kabiyesi iku baba yeye lati rọ ọ loye gẹgẹ bi Mayegun ilẹ Yoruba.

Àkọlé fídíò, 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC

Ó ní ìdí tí àwọn fi fẹ́ kí wọ́n gba oyè lọ́wọ́ Máyégún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ní pé ìwà tó hù kò bá ìlànà oyè tó jẹ́ lọ nítorí náà, Aláàfin Ọyọ Ọba Lamidi Adeyemi gbọ̀dọ gbà á lọ́wọ́ rẹ.

Lórí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rún Náírà ti Murphy gbà lọ́wọ́ K1, o ní láti le dáàbò bo ẹ̀mi rẹ nítori túlàsì ni wọ́n fi fún un ni owó náà. Tí ọ̀rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, ó ti pọndandan ki ènìyàn dáàbò bo ẹmi ara rẹ náà.

Lẹ́yìn tí Wasiu Ayinde bá wá ti gbé ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ̀ náà bèrè fún ni àwọn yoo tó mọ̀ boya àwọn yóò dá owó náà padà bi bẹ́ẹ̀ kọ́, owó ọhun kò tí tó ǹkan ti àwọn fi ṣe ìtọ́jú MC Murphy.

Ó rọ gbogbo olórin láti so ewe agbéjẹ́ mọ́wọ́ lórí bi wọ́n ṣe máa n huwa sí àwọn akọròyìn, ìwà ìyànjẹ to fi mọ ìwà àitọ sí àwọn akọròyìn ní Naìjíríà.

Bákan náà ló fi kún un pé, ìdáhùn ọkan lára amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ K1 to bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ tó sí ló àwọn ọ̀rọ̀ kan, ẹgbẹ náà ni láti mọ̀ bóya òun gan ló fún un láṣẹ lati sọ̀rọ̀.

Bákan náà ni wọ́n gbọdọ̀ tọ̀rọ̀ àforijì lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àwọn ọmọ FIBAN kò gbọdọ̀ lo orin Wasiu Ayinde mọ́ lẹ́yìn ìfìyàjẹní Murphy- FIBAN

Àkọlé fọ́nrán ohùn, "Wasiu Ayinde fi bàtà tẹ̀ mí lórí àti imú mọ́lẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbá mi létí"

Ẹgbẹ awọn oniroyin aladani, FIBAN ti kede pe ọmọ ẹgbẹ wọn kankan ko gbọdọ lo orin Wasiu Ayinde kankan mọ lori eto wọn.

Aarẹ ẹgbẹ FIBAN, Desmond Nwachukwu lo fi lede ninu atẹjade kan lati fesi si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laarin Wasiu Ayinde ati oniroyin Wole Sorunke ti wọn n pe ni MC Murphy.

Nwachukwu ni iṣẹlẹ naa ko dun mọ awọn ninu nitori pe ki i ṣe igba akọkọ ni yii ti Kwam 1 yoo ma hu iru iwa bayii ni igba de igba.

O ni ọrọ abuku ni asoju Kwam 1, Kunle Rasheed sọ nipa iṣẹlẹ naa fun BBC News Yoruba nibi to ti sọ fun ẹgbẹ FIBAN lati sa ipa wọn lori iṣẹlẹ naa, koda wọn le e gbe awọn lọ si ileẹjọ.

''Ma a bẹ awọn ọmọ ẹgbẹ lati da ọrọ Rasheed nu, nitori ko si otitọ kankan to sọ pẹlu ọrọ kubakugbe to sọ si ẹgbẹ FIBAN.''

''Rasheed tabuku lu wa nitori pe o pe wa ni ẹgbẹ ti ko ni oye nipa iṣẹ to n ṣẹ''

''Nitori naa ni bayii, ko si ọmọ ẹgbẹ wa kankan ti yoo lo orin Kwam 1 lori eto wa kaakiri iwo oorun orilẹede Naijiria.''

''Bakan naa ni a ti ranṣẹ si awọn adari ileeṣẹ radio ati amọhunmaworan lati tẹlẹ aṣẹ wa lati maṣe lo orin Kwam 1 mọ.''

Ẹgbẹ FIBAN fi kun un wi pe awọn yoo ṣewode lọ si aafin ti Alaafin Oyo lati fi aidunnu wọn han si iwa ifiyajẹni ti Kwam 1 n wu lawujọ.

Bakan naa ni awọn yoo bẹrẹ lọwọ Alaafin lati rọ ọ loye Mayegun ti Ilẹ Yoruba nitori ihuwasi rẹ ti ko ba ọna asa ati iṣe Yoruba mu.

Kwam 1: Ọmọṣẹ́ Wasiu ni MC Murphy, tó bá fẹ́ lọ sílé ẹjọ́ kó nìsó níbẹ̀- Alákòso orín K1

Ni owurọ ọjọ Abamẹta ni ariwo gba ilẹ kan pe, ilumọọka akọrin Fuji ati Mayegun ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde Mashall, ti ọpọ eeyan mọ si Kwam 1, gba gbajumọ agbohunsafẹfẹ kan leti loju agbo.

Alákòso orín Wasiu Ayinde Mashall, Adebayo Olasoju to ba BBC Yoruba sọrọ lórí fóònù ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ kìí ṣe èyí tó yẹ ki ó jáde rárá nítóri, ọmọ iṣẹ́ K1 ni MC Murphy.

Kété ti ọrọ náà bẹrẹ si ni ran ka ni BBC kan si àwọn to jẹ́ ti K1, nítori owe àgbà ló sọ pé agbẹ́jọ́ ẹnikan dájọ àgbà òṣìkà ni.

"Tí ọ̀rọ̀ bá ṣẹlẹ̀ láàrín K1 àti MC Murphy ti Murphy kò si le pé Wasiu Ayinde to wá gbé ẹjọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn , òun ló mọ"

"Tí àwọn FIBAN bá sì fẹ́ lọ sí ilé ẹjọ́, kí wọ́n nìsó níbẹ̀" Ọ̀rọ̀ ti a ń múgbọ́ jú ti Murphy lọ, a ò ni ẹjọ́ kankan ti a fẹ́ bá a rò"

Alakoso orin Kwam 1, Adebayo Olaasoju sọ fun BBC Yoruba pe, ọrọ naa ko ri bẹẹ rara nitori Kwam 1 ko lee gba ẹnikẹni leti rara.

Àkọlé fídíò, Wo Adigun ọmọ ọdún mẹ́rin tí òwe Yorùbá àti ìtúmọ̀ gbó lẹ́nu rẹ̀ ju tìrẹ̀ lọ

"Awọn wo lo na a, se Kwam 1 ni. Ọmọ Wasiu ni MC Murphy now, ko si yẹ ko gbe ọrọ naa lọ sọdọ awọn akọroyin, oun n gan mọ pe oun ko sọ ootọ bi ọrọ naa se ri.'

Bakan náà BBC bá ilumọọka agbohunsafẹfẹ naa ti wọn pe ni Wole Sorunke, ti ọpọ eeyan mọ si MC Murphy, ẹni tii se oludari eto gbogbo nileesẹ radio Fresh FM to wa nilu Abeokuta náà sọ̀rọ̀.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun Olu tilu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ ni isẹlẹ naa ti waye, lasiko ti wọn pe Kwam 1, ko wa kọrin nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe Mayegun se agbohunsafẹfẹ yii, bii ọsẹ tii se oju, to si fi se ẹlẹya lori ọrọ ti ko to nnkan.

Ọna lati fi idi otitọ mulẹ nipa iroyin yii, lo mu ki BBC Yoruba kan si MC Murphy, ka le mọ bi isẹlẹ naa se waye.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Murphy ni lootọ ni ọmọ isẹ gbajumọ olorin Fuji , Wasiu Ayinde, to pe orukọ rẹ ni KC gba oun leti, ti Wasiu Ayinde funra rẹ gan si fi bata tẹ oun ni ori ati ẹnu mọlẹ.

O fikun pe, lẹyin to tẹ oun lori ati ẹnu tan, ni Wasiu to wa sẹsẹ tun n gbe oun lori dide, eyi ti ko bojumu rara.

"Mo kọkọ n wo pe se ẹgbọn n ba aburo rẹ wi ni abi ibo ni mo ti se asise? Abi nnkan kan sẹlẹ ti Alhaji ko ri ni, abi nnkan ti ko yẹ ki wọn sọ fun wọn ni wọn gbọ ni, ko tiẹ ye mi."

Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Instagran/kingwasiuayindemarshal

Murphy ni oun lọ siwaju Kwam 1 lati nawo fun ni, ki o le ki ẹnikan ti oun n ba se onigbọwọ, ki oun si fi ọrọ ẹni naa to leti pe onitọun fẹ wa na lowo fun loju agbo.

Amọ o ni, Wasiu Ayinde ko dahun, ti oun si sọkalẹ loju agbo naa.

"Sugbọn bi mo se sọkalẹ ni mo gbọ gba leti mi, ti wọn si da mi dọbalẹ, ti wọn n fi bata tẹ mi lori mọlẹ. Gbogbo awọn ero to wa loju agbo lo binu, ti wọn si kuro nibẹ.

Murphy ni Olu ti ilu Itori tawọn lọ ba se ayẹyẹ ti bẹ oun, nitori oloye ni oun nilu Itori, oun si ni Aarẹ Amuludun fun gbogbo ilu Itori.

Àkọlé fídíò, Yomi Fabiyi: Fíìmù ‘Owó orí ẹlẹ́wọ̀n’ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìpọ́njú làá mọ ọ̀rẹ́

"Mo maa n promote awọn olorin, mo si mọ pe Wasiu gbọ ọrọ ti ko yẹ ni nitori ko ye mi nipa oun ti wọn gba mi leti si, kii si se eeyan bẹẹ."

Nigba ta bi pe ki lo fẹ se nipa isẹlẹ yii, MC Murphy ni isẹlẹ naa ti kọja agbara oun, ti olu ile ẹgbẹ awọn agbohunsafẹfẹ ni Naijiria, FIBAN, si ti tẹsẹ bọ ọrọ naa.

"Wasiu Ayinde funra rẹ gan ti n bẹ mi, to si ti pe mi pe, ki n ranti pe oun ni ẹgbọn oun. Ti Wasiu ba na mi ni kọrọ, o to eeyan to le na mi, amọ eyi to se ni gbangba lo ku diẹ kaa to.

Ọlọrun kan fẹ ki iru nnkan bayii sẹlẹ ni, ki Alhaji Wasiu ma baa se iru nnkan bayii mọ."

Àkọlé fídíò, Ìṣẹ̀lẹ̀ Kàyéèfì: Ìpáǹle tú Abass Owonikoko sí ìhòòhò ayé, kó tó gba kéú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

O wa rọ awọn akọroyin atawọn adari eto, ta mọ si MC pe, ki wọn maa bọwọ fun ara wọn, ki wọn ma si toju bọ ayẹyẹ ti wọn ko ba pe wọn si, tori awọn abuku bii eleyi.

Àkọlé fídíò, Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú