Funke Akindele: Òun àti ọkọ rẹ gba ìdáríjì lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko

Funke Akindele ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/FunkeAkindele

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fun gbajugbaja oṣere, Funke Akindele ti gbogbo eniyan mọ si Jenifa ati ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello, JJC Skillz ni aṣẹ ma a lọ lailẹbi lọwọ ipinlẹ Eko.

Funke Akindele ati ọkọ rẹ ni wọn jẹbi ẹsun ṣiṣẹ ayẹyẹ ọjọ ibi tako ofin to de itankalẹ arun Coronavirus ni Oṣu Kẹrin, ọdun 2020.

Ti ijọba si fun wọn ni idajọ lati ṣiṣẹ ilu gẹgẹ bi iya fun ofin ti wọn tẹ oju rẹ mọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sanwo-Olu ninu atẹjade to fi lede ni Ojọ Ẹti ni, awọn tu awọn ọkọ ati iyawo silẹ, lẹyin imọran lati ọdọ ajọ Advisory Council on Prerogative of Mercy.

Funke Akindele ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/FunkeAkindele

Ijọba fi lede wi pe aṣẹ naa tẹle iwe ofin ipinlẹ naa to gba gomina laaye lati ṣe bẹẹ (Section 212 1& 2 ) labẹ ofin ọsun 1999.

Bakan naa ni Gomina Sanwo-Olu da awọn ẹlẹwọn mẹrindinlọgọta silẹ ni awọn ọgba ẹwọn kaakiri ipinlẹ naa.

Olotu eto idajọ nipinlẹ Eko, Kayode Oyekanmi ti wa rọ awọn to jẹ anfaani yii lati yẹra fun iwa ọdaran ki wọn si tẹle aṣẹ ati ofin ilu.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Ni oṣu Kẹrin, ọdun 2020 ni ajafẹtọ ọmọniyan to tun jẹ agbẹjọrọ agba rọ gomina Sanwo-Olu lati da Funke Akindele ati ọkọ rẹ silẹ.

Nollywood Roundup: Mó ti ṣe iṣẹ́ abẹ lóòtọ́ ṣùgbọ́n kìí ṣe ìdí tàbí ọmú - Iyabo Ojo

Iyabo Ojo ní lóòtọ́ ni òhun ti ṣe iṣẹ́ abẹ rí, ṣùgbọ́n kìí ṣe pé nítorí ọkùnrin tàbí afẹ́ ayé, ṣùgbọ́n "nítorí pé mó fẹ́ ni ìgboyà nínú ara mí ni mó ṣe ṣe e".

Iyabo Ojo fi idi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásíkò tó ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú BBC. O ní nígbà ti òun bi àkọbi ọmọ òun ni òun ṣe àkíyèsí pé, ọ̀rá pọ̀ jù ní ìkù òun, òun si ṣe ìpinnu pé ti òun bá ti ni owó lọ́wọ́ òun yóò lọ ṣe ǹkan ti o wú òun.

Kìí ṣe gbogbo òṣèré tíátà náà ló n fí ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yin ri owó, ọ̀pọ̀ wà ló n ṣe ìṣẹ́ ọwọ́n rẹ̀ pẹ̀lú oníruuru òwò láti rí owó

Oríṣun àwòrán, Iyaboojofespris/instagram

Ó ní nígbà tí owó díẹ̀ yọ sọ́wọ́ ni òun gba ọ̀nà Turkey lọ láti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ náà, "àsìkò yìí ni ìròyìn gbòde nítori mo ṣe àìsàn lẹyìn iṣẹ́ abẹ náà."

"Àwọn dókìtà ní mo ṣàìsàn nítorí àwọn èròjà tó má n bá ààrùn jà lára mí kò pọ tó, Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run."

Àkọlé fídíò, Lákọ lákọ nìbọn ń ró níbí táwọn Ọlọ́pàá àti Sọ́jà tí ń gbáradì fún ìdìbò Ondo

Gbájúgbaja òṣèré tíátà Yoruba náà sàlàyé pé ariwo ti àwọn ènìyàn ń pa lóríI pé, àwọn òṣèré tíátà n kọ́lé ńla, tàbi wọ́n ń ra ọkọ̀, kìí ṣe gbogbo òṣèré ni ọkùnrin ń kówó fún kí wọ́n to ṣe aṣeyọrí.

Kìí ṣe gbogbo òṣèré tíátà náà ló n fí ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yi ri owó, "ọ̀pọ̀ wà ló n ṣe ìṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú oníruuru òwò láti rí owó.

Nkechi Blessing ati okunrin to fun ni kẹkẹ

Oríṣun àwòrán, Nkechi /Instagram

Nkechi Blessing

Nkechi Blessing Sunday náà ra kẹ̀kẹ́ ìrìnsẹ̀ fún ọkunrin kan to ni ìpèníja ara.

Nkechi Blessing ni, ọkunrin kan to n jẹ́ Busari Taofeek Ademola kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí orí intagram òun pé òun nílò kẹ́kẹ̀ ìrìn ti àwọn arọ máa ń lò.

"mo lọ sí ibi àtẹ̀jíṣẹ́ rẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti ri pé ó ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí mi tẹ́lẹ̀ tó tọrọ kẹ̀kẹ́, ṣùgbọ́n Ibadan ló n gbé" Nkechi ni ká ma fa ọ̀rọ̀ gún òun ke sí ènìyàn òun kan tó ń gbé ni Ibadan.

Gbájúgbajà òṣèré Nollywood náà ni kété ni òun ti fi kẹ̀kẹ́ náà àti àwọn ǹkan elò míràn ránṣẹ́ si i.

Nkechi Blessing ni kìí ṣe pé òun kọ èyí kí ẹnikẹni le sọ pé ènìyàn dáada ni òun, ṣùgbọ́n òun gbé fọ́ran rẹ̀ síta fún àwọn ènìyàn láti náwọ ìrànwọ́ si i.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Shaffy Bello

Nollywood Roundup: Mó ti ṣe iṣẹ abẹ lóòtọ́ sùgbọ́n kìí ṣe ìdí tàbí ọmú-Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, SHAFFYBELLO/INSTAGRAM

Nínú ọ̀sẹ̀ yìí bákan náà, gbájúgbaja nínú eré tíátà Nollywood òyìnbó àti Yoruba tó tún jẹ́ olórin, náà ṣe ọjọ́ ìbí.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe kọ ọ́ sójú òpó instagram rẹ̀ lówùrọ̀ òní, Shaffy Bello ni, ilé olóke márùn dara gan ni.

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ nínú eré tíátà ló n ki i kú ewu ọjọbi ààdọ́ta ọdún ti àwọn ọlóyìnbó n pè ni "Golden Jubilee".

Iyabo Ojo: Ololade Abuta ní káwọn gbéborùn dákẹ́ lórí jeep túntún Boss Lady

Iyabo Ojo ati ọkọ Jeep rẹ tuntun

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris

Gbajumọ olokoowo kan nilu Eko, Ololade Abuta ti kede fun araye pe kawọn eeyan to sọ ohun ti oju wọn ko to nitori ọkọ Jeep tuntun ti Iyabo Ojo sẹsẹ ni.

Ololade, nigba to n kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ lọsan Ọjọru, tun salaye pe ọpọ ahesọ ọrọ ni oun ti gbọ nipa ọkọ naa.

O ni oun fẹ wa kede fun araye pe owo oju oogun oju oun ni oun fi ra ọkọ naa bii ẹbun fun Iyabo Ojo nitori awọn oore kan to ti se fun oun.

Abuta ni " Iya to se atilẹyin wa ni mo ra ọkọ Range Jeep fun, ẹnikẹni ti ko si seranwọ fun wa la ra kaadi ipe fun, eyiun Recharge card.

Iy

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris

Lonii Iyabo Ojo, mo mọ riri rẹ fun obinrin rere to jẹ, lootọ ni o ko pe nitori ko si ẹda to pe amọ o ni ọkan to dara, to si jẹ ọkan lara awọn eeyan ti mo mọ riri wọn."

Ololade ni oun kii se ẹni to maa n sọrọ lori ayelujara tabi maa ko ko bẹẹrẹ fun ẹnikan nitori atẹnujẹ amọ Iyabo Ojo jẹ eeyan kan to yẹ lẹni ti a gbe sla fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

O fikun pe ojo ti n pa igun oun ati Iyabo bọ, ọjọ ti pẹ, to si ti to ọdun mẹẹdogun tawọn ti mọ ara awọn.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

O ni yatọ si pe Iyabo jẹ oninure, se lo tun fi gbogbo ara se atilẹyin fun oun, ọrọ si pọ ti oun fẹ sọ nipa rẹ, amọ ti oun ba kọ silẹ, ọpọ eeyan ni ko ni le ka a.

"Hen hen, mo gbọ pe awọn eeyan kan n sọ ahesọ ọrọ kiri pe ọkunrin kan lo ra mọto Jeep naa fun Iyabo Ojo, to wa sọ fun mi pe ki n kede pe emi ni mo ra fun oun.

Nigba ti mo gbọ, mo rẹrin arintakiti amọ nigba to ya, n ko le rẹrin mọ, ti aanu irufẹ awọn eeyan naa si n se minitori pe o seese ko jẹ ipo ailowo lọwọ wọn lo faa, ti wsn se n ronu bẹẹ tabi pe wọn jẹ ahun."

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Ololade wa gbadura pe Ọlọrun yoo bukun fun wa de ipo to jẹ pe ati ra iru ẹbun bii mọto nla bayii ko ni jọ wa loju rara nigba ta ba ri owo ra a.

Kia naa si ni Iyabo Ojo funra rẹ ti fesi si ọrọ naa, to si ni oun nifẹ Ololade pupọ fun ikede to se naa.