Iyabo-Fathia Fracas: Ojo ní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà wa kọjá àhesọ tẹ́ ń gbé kiri, ó jinlẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ni

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris
Egbirin ọtẹ lọrọ awọn isẹlẹ to n waye lagbo isẹ tiata lẹnu lọọlọ yii, baa ti n pakan, ni omiran n ru.
Eyi ko sẹyin gbọnmisi omi oto to maa n waye laarin awọn osere tiata, paapa awọn obinrin wọn, to si maa n fa gbodo n rosọ.
Lọdun to kọja, bẹẹ ba gbagbe, aawọ ja ranin-ranin nilẹ laarin Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin, to dogun, to dọdẹ, koda ọrọ naa de ọdọ ọlọpa ati awọn asaaju isẹ tiata pẹlu, ki wọn to bomi pana rẹ.
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn
- Ẹ má jẹ́ kí ayélujára tàn yín jẹ́, mẹ̀kúnnù lọ̀pọ̀ àwa òṣèré tíátà - Iyabo Ojo
- Òótọ́ ni Iyabo Ojo ń sọ́! Ìdójútì gbàá ni kí Òṣèré máa tọrọ owó tórí àìsàn - Femi Adebayo
- Toyin Abraham, Femi Adebayo bá Funke Akindele kẹ́dùn
Sugbọn o dabi ẹni pe awọn osere tiata lobinrin miran tun ti n palẹ ogun mọ, ti aawọ miran tun ti n rugbo bọ laarin awọn ilumọọka kan laarin wọn, paapa ta ba wo bi wọn se n sọ oko ati ogulutu ọrọ si ara wọn loju opo Instagram awọn ti ọrọ naa kan.

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
Iyabọ Ojo lo kọkọ kọ nkan loju opo Instagram rẹ, eyi to fi n pa asamọ si akẹẹgbẹ rẹ kan lagbo tiata to n se ọjọ ibi lọjọ lọjọru, ọjọ karun osu keji , bi o tilẹ jẹ pe ko darukọ onitọun.

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
Amọ wọn ni olowe lọrọ n ba wi, ẹni to ba si wo atupalẹ ọrọ naa yoo mọ pe Fathia Balogun ni obinrin kansoso to se ọjọ ibi lọjọ naa, bi o tilẹ jẹ pe oun ati ọkọ rẹ, Saheed Balogun ni wọn dijọ see.
- A kò ní fi adé wa sílẹ̀ nítorí Olubadan - Àwọn Ọba 27
- Arẹ́májà kò sí, Olubadan fi tìlù-tìfọn kí àwọn ìjòyè káàbọ̀ lẹ́yìn ọdún méjì
- Amotekun: Kí ni iṣẹ́ tí Amotekun yóò máa ṣe gangan?
- Ohun tó ti yá kan kìí pẹ́ mọ́, fọ́ọ̀mù ìgbaniṣíṣẹ́ fún Àmọ̀tẹ́kùn dé!
- Àgbékalẹ̀ Amotekun dára torí agbára òògùn àwọn baba wa kò dínkù tàbí parẹ́ - Peter Fatomilola
- Iléẹjọ́ gíga Akure kọ̀ láti gba onídùróó olórí ìjọ Sotitobire
- Mò ń tọ̀ s'ára ni mo fi gba ara à mi l'óko ẹrú ní Oman
- Ẹ fi èmi àti àwọn alága káńṣù APC sílẹ̀, ká yanjú aáwọ̀ wa nítùbí-ǹnùbí - Makinde bẹ iléẹjọ́
Iyabọ Ojo, ẹni to ki gbogbo awọn ọkunrin yoku to se ọjọ ibi lọjọ naa ni ko ki Fathia Balogun amọ dipo bẹẹ, ohun to kọ soju opo Instagram rẹ niyi dabi owe to fi n sọko ọrọ si onitọun.
" Gbogbo igba lo maa n ba mi lojiji amọ ọrọ rẹ ko ya mi lẹnu nitori pe iwọ ni agbaaya akọkọ ni agbo tiata Nollywood..., o ko bọwọ fun ara rẹ rara, o maa n jowu awọn akẹẹgbẹ rẹ to kere si ọ, to si maa n dibọn bii ẹni pe o nifẹ awọn to n ri anfaani kan abi omiran lara wọn sugbọn lẹyin o rẹyin, o kii jẹ olotitọ si wọn, o si kuku si maa tẹ bọ ni."
Iyabo tẹsiwaju pe "Lẹyin gbogbo nkan ti mo se fun ọ lọdun meji sẹyin nigba ti mo se ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ fun ọ ni orilẹede Turkey, o tun lọ tẹnu-bọlẹ lẹyin mi fun awọn akọroyin pe mo daku fun ọjọ mẹta! O fẹ ki n ku tori pe o mọ pe mo sisẹ abẹ, mo mọ pe o n reti pe maa ku...idi ree ti o ko fi wa ki mi lẹyin naa sugbọn Ọlọrun mi ju ọ lọ, o lagbara ju ẹ lọ, Ọlọrun mi ja iwọ ati ikọ rẹ kulẹ, mo si wa laaye."

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
" Ajẹ ni ẹ o, abo kiniun ni mi, to maa n bori ogun lọjọkọjọ, ko si bo se tiraka to lati fa mi walẹ tabi ba orukọ mi jẹ ninu ẹmi... imọlẹ ati okunkun ko le duro sibi kannaa, mo si ni igboya lati sọ fun ẹ pe, eeyan buruku ni ẹ, pada lẹyin mi Ajẹ. Ma gbadun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni Islandlounge7, ko si ranti pe, emi ni mo sọ bẹẹ."
Wayi o, oniruuru itumọ ni awọn eeyan ti ba Iyabọ wa si ọrọ rẹ yii, ti ọpọ wọn si ni Fathia Balogun lo n ba wi tori pe oun lo se ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọta rẹ ni Turkey lọdun 2018 pẹlu Iyabọ Ojo.

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
Ọpọ eeyan lo ti wa n beere pe ki lo faa ti tirela fi gba aarin awọn tẹgbọn-taburo ati ọrẹ yii kọja, amọ awọn eeyan miran ni ija wọn lo seese ko ni nkan se pẹlu pe, wọn gba ọkunrin mọ ara wọn lọwọ.
Sugbọn Iyabọ tun ti kede loju opo Instagram rẹ bayii pe laelae, ohun ti yoo gbẹyin ti ohun lee se ni lati maa du ọkunrin, boya o ti niyawo ni abi bẹẹkọ, mọ obinrin kankan lọwọ, nitori ko jọ rara, ma kan kọti ikun si onitọun ni.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O fikun pe "Ohun to n sẹlẹ lagbo tiata wa kọja gbogbo ahesọ ọrọ tẹ n kọ kiri, o si kọja ohun to lee ye yin, huu, o jinlẹ gan ni ooo... o ti n waye lati aye papa Ogunde, yoo si maa wa bẹẹ titi laelae ni, ko si seese ki eeyan mura silẹ de, amọ bo ba se n gbona si, mo ti mura silẹ."
Too, Ọlọrun nikan lo tun mọ ibi ti eyi to tan de, BBC Yoruba fọwọ lẹran, o n woye ohun to n waye lagbo tiata.













