Operation Amotekun: Amọ̀tẹ́kùn ṣetán láti gbérasọ, fọ́ọ̀mù ìgbaniṣíṣẹ́ ti dé!

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission
Ohun to ba ti ya kan, kii pẹ mọ, fọọmu igbaniṣiṣẹ fun ẹṣọ alaabo lawọn ipinlẹ Yoruba, Amọtẹkun yoo jade lọsẹ to n bọ.
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo fọrọ yii lede lati ẹnu oludamọran rẹ lori ọrọ aabo, Alhaji Jimoh Dojumo.
Gomina Akeredolu ṣalaye pe gbogbo eto lo ti to bayii lati gbe fọọmu naa sita.
- Amotekun: Kí ni iṣẹ́ tí Amotekun yóò máa ṣe gangan?
- Tinubu kò ṣékú, kò ṣé ẹyẹ, o n dibọn ní lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Amotekun - Fani Kayode
- Àwọn adigunjalè yabo bánkì méjì nípìnlẹ̀ Ondo, ènìyàn bi i mẹ́ta kú
- 'Ìbànújẹ́ ló jẹ́ láti rí ìyá àti ọmọ tó ń fẹ̀sẹ̀ rìn ní òru l'Eko nítorí àìsí kẹ̀ẹ̀kẹ́ àti ọ̀kadà'
- Iléẹjọ́ gíga Akure kọ̀ láti gba onídùróó olórí ìjọ Sotitobire
- Ọlọ́pàá tó pa èèyàn pokùnso lọ́jọ́ kejì tó dé àhámọ́ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́
- Ẹ fi èmi àti àwọn alága káńṣù APC sílẹ̀, ká yanjú aáwọ̀ wa nítùbí-ǹnùbí - Makinde bẹ iléẹjọ́
''Awọn ọba alaye atawọn olori awujọ ni yoo ṣe oniduro fawọn eeyan wọn to ba fẹ darapọ mọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun,'' Akeredolu lo ṣalaye bẹẹ.
Laipẹ yi ni awọn gomina guusu iwọ oorun ṣepade pẹlu igbakeji aarẹ, Yemi Oṣibajo ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lati sọ asọyepọ lori eto naa.
Malami ti kọkọ sọ pe, eto Amọtẹkun tawọn gomina ipinlẹ Yoruba gbe kale ko si ninu iwe ofin Naijiria.

Ọpọ awọn ilumọọka agbẹjọro atawọn ajafẹtọ omoniyan lo ti ṣatilẹyin fun eto Amọtẹkun lẹyin ti tako agbekalẹ eto naa.
Ọjọ kẹsan an oṣu kinni lawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe agbekalẹ Amọtẹkun ni olu ilu ipinlẹ Oyo, Ibadan.












