Lagos okada ban: Ìwọ́de yóò wáyé pẹ̀lúù àkòrí #OccupyLagos

Oríṣun àwòrán, others
Oludari #OccupyLagos to n pe fun ifẹhọnu han lori bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe gbegile kẹkẹ ati ọkada ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba.
Ọmọsalewa Badejo ti ni ijọba Eko ko se ohun to dara fun awọn ara ilu nitori iya ati inira lo mu de fun awọn araalu.
Badejọ sọ pe ni ọjọ Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ni ifẹhọnu han naa yoo waye ni Eko Atlantic Hotel lasiko ti awọn eniyan ba n ṣe ere sisa maratọọnu to ma n waye ni ipinlẹ Eko l'ọdọọdun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
O ni awọn ti pese eto aabo to peye fun awọn afẹhọnu han ati wi pe ko ni si wahala tabi rogbodiyan lasiko naa nitori awọn yoo sẹ e ni irọwọrọsẹ.
Ọmọsalewa lasiko to n ba BBC sọrọ sọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun lati ri iya ati ọmọ to n sunkun, nigba ti wọn n fi ẹsẹ rin lọ ni oru nitori ko si ọkọ, bẹẹ ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ peleke si ni ipinlẹ Eko.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Oludari #OccupyLagos ni awọn kọ igbesẹ ijọba nitori o yẹ ki wọn pese ọna miran lati koju aisi ọkada tabi kẹkẹ fun awọn eniyan lati lo, ki wọn to ko wọn kuro nilẹ.
O ni ko bojumu ki ijọba má pese eto irinna to gbooro fun awọn araalu, ki wọn tun fi iya jẹ wọn nitori wọn yoo pẹ de ibi iṣẹ wọn, eleyii ti o le e mu wọn ma ṣe bo ti tọ ni ibi iṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Badejo wa rọ ijọba lati tun ero wọn pa, ki wọn si da kẹkẹ ati ọkada pada si igbooro lati mu irọrun ba awọn eniyan ni ipinlẹ Eko.
Lori ọrọ wi pe ọpọlọpọ awọn ọlọkada naa lo n sare asapajude, arabinrin naa ni ijọba lẹtọ lati la wọn lọyẹ lori bi o ṣe yẹ ki wọn ṣe loju popo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bakan naa ni o fikun wi pe, nitori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni ipinlẹ Eko to ti buru si, ijọba gbọdọ tun awọn oju ọna ṣe, ki wọn si pese oju ọna reluwe ti yoo ma a gbe awọn eniyan.
Oludari #OccupyLagos ni ti ijọba ba pese awọn eto yii , igbe aye awọn eniyan a tunbọ dara si, eleyii ti yoo mu igbeleke ba ipinlẹ Eko.