Sim Card Regulation: Amòfin kan ní iye ‘Sim Card’ ta bá ní, kò ní ǹǹkan ṣe pẹ̀lu ìwà ọ̀daràn

Sim Kaadi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọ Naijiria kan ti sọ pe, ọrọ iye Kaadi ibaraẹnisọrọ, Sim Card ti eeyan n lo kọ lo yẹ ko jẹ ijọba logun bayii, bikoṣe bi o ṣe maa ṣakoso awọn ileeṣẹ ibanisọrọ.

Ajafẹtọẹni Kunle Wiseman Ajayi lo sọ ọrọ naa fun BBC Yoruba, lẹyin ti minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati ọrọ aje ori itakun agbaye, Isah Pantani sọ pe, ijọba n gbe igbesẹ lati ri dena ki eeyan kan lo ju kaadi ipe mẹta lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kunle ni oun to yẹ ki ijọba ṣe ni ko ba awọn awọn ileeṣẹ ibanisọrọ wi lori awọn aṣemaṣe ti wọn n ṣe, paapa bi wọn ṣe ma n ja owo awọn onibara wọn ni ijakuja.

Ẹrọ ibaraẹni sọrọ

Oríṣun àwòrán, Others

O ṣalaye pe, ootọ ni pe awọn eeyan kan n lo ẹrọ ibanisọro lati wu iwa ibajẹ, ṣugbọn ko digba ti ijọba ba gbe gbendeke le oye sim kaadi ti eyan n lo ki eto abo to ṣe dede.

Ajafẹtọẹni ọhun tẹsiwaju pe "Awọn eeyan n ṣe oriṣirisi ibajẹ lai lo ẹrọ ibanisọrọ, ko di igba ti wọn ba sọ pe eeyan kan ko gbọdọ lo ju simu mẹta lọ ki eto abo ilẹ wa to ṣenu ire."

O ni kaka ki ijọba maa fi akoko ṣofo lori iye simu ti eeyan nlo, n ṣe lo yẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si iwa jibiti ti awọn ileeṣẹ ibanisọrọ n hu si awọn ọmọ Naijiria.

Ajayi lero pe nnkan to le din iwa ibajẹ ku ni ki ijọba mu aye dẹrun fun awọn eeyan, ki wọn si fi ọrọ siimu silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe siimu kan ṣoṣo ni ajafẹtọ ẹni naa n lo, o ni oye owo ti oun n nna lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ loṣu le ni ẹgbẹrun un lọna ọgbọn naira.

Ẹrọ ibaraẹni sọrọ

Oríṣun àwòrán, Others

Amofin agba Dayo Akinlaja ni, labẹ ofin gbogbo ọmọ Naijira ni ẹtọ lati sọrọ bo ṣe wuu, nitori naa, ti eeyan ba ni idi pataki lati ni ju siimu mẹta, ko yẹ ki ijọba sọ pe eeyan ko gbọdọ lo siimu mẹta lọ.

O ni ẹni to ba fẹ wu iwa ọdaran lee huwa ọdaran, bo ba n lo kaadi ipe kan tabi ju bẹẹ lọ.

Akinlaja sọ pe, iwa ọdaran ko ni nnkan ṣe pẹlu iye siimu ti eeyan n lo.

Àkọlé fídíò, Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Torí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

O ṣalaye pe oun to yẹ ijọba ṣe ni lati maa lo ẹrọ igbalode lati tọpinpin awọn ọdaran, nitori simu kan to eniyan lati ṣe iṣẹ ibi.

Amofin ọhun pari ọrọ rẹ pe "Ti eeyan ba ni simu meji tabi mẹta, emi o mọ bi iyẹn ṣe lee din iwa ọdaran ku."