Fathia Balogun, Toyin Abraham bá Funke Akindele Kẹ́dùn ikú bàbá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @funke
Awọn oṣere ti n ba Funke Akindele kẹdun iku baba rẹ lẹyin ti oṣere naa kede pe baba rẹ ti pa ipo da lorii ikanni Instagram rẹ.
Ninu awọn oṣere ti wọn kọkọ ki Funke Akindele kuu ọrọ eeyan ni Toyin Abraham ati Fathia Williams.
Iyabo Ojo naa o gbẹyin ninu awọn oṣere ti wọn na Funke Akindele kẹdun lorii ikanni Instagram rẹ.

Oríṣun àwòrán, @funke
Funkẹ Akindele sọ bi oun ṣe gbiyanju to ṣugbọn gbogbo ẹda lo wọ agbada iku ni ọrọ baba rẹ pada ja si.
Lola Idije, Fathia williams, Lala, Awelewa atawọn mii n ki aya Bello ku ara fẹraku.

Oríṣun àwòrán, @funke









