Sotitobire àti àwọn wòlíì ọmọ Nàìjíríà míràn tó ti lọ sẹ́wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn

Kìí ṣe ìròyìn tuntun mọ́ pé, wọ́n ti dájọ ẹ̀wọ̀n gbéré fún Alfa Babatunde ti ìjọ Sotitobire ni ìlú Akure tíí ṣe olúùlú ìpínlẹ̀ Ondo lórí ẹsùn ìjímọgbé.
Sùgbọ́n ṣe ẹ mọ̀ pé kìí ṣe òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò dèrò ẹwọn nítori ẹsùn ìwà ọdaran tó wáyé nínú ọgbà ilé ìjọsin wọn
Onírúurú ẹ̀sùn si ni ó ti gbé ọ̀pọ̀ dé ọgbà ẹwọn lẹ́yìn ti wọ́n ṣe ẹjọ wọ́n tán, láti orí ìpànìyàn dóri ìfipá bánilòpọ̀ àti olè jíjà
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Ìdájọ́ ẹ̀wòn gbére kò ní kí Wòlíì Sotitobire má lọ sí ilèẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn - Agbẹjọ́rò Pásítọ̀ Alfa Babatunde
- Oníṣẹ́ ọwọ́, oníṣẹ́ àdáni, awakọ̀, ẹ wo ọ̀nà láti gba lára owó ìrànwọ́ Covid-19 tí ìjọba gbékalẹ̀
- Wo ọ̀nà àbáyọ sí bo ṣe ń han‘run
- Ìdí ọlà mí mọ́, bí mo sì ta gbogbo dúkìá mi, kò ní kí òṣì tán ní Nàíjíríà - Dino Melaye
- Dapo Abiodun yan Laycon ní aṣojú pẹ̀lú ẹ̀bún ₦5m àti ilé oníyàrá mẹ́ta
- Ọkọ̀ agbépo subú lọ́nà Badagry, súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ gbòde - LASEMA
Wòlíì Alfa Babatunde, ìjọ Sotitobire

Alfa Babatunde ti ìjọ Sotitobire yìí ni ó kẹyin lasiko ti a n kọ iroyin yii nínú àwọn tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ sí lara àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti aaje ìwàbàjẹ́ pada ṣímọ́ lórí pé wọ́n jẹ bi ẹsùn ọ̀daran tí wọ́n fi kàn wọ́n.
Olùdásílẹ̀ Sotitobire Miracle Centre, Wòlìí Babatunde tí n lọ ilé ẹjọ bọ̀ láti bí ọdún kan nígbà ti ẹjọ́ náà bẹ̀rẹ̀.
Ọjọ́ kẹwàá oṣù kọkànlá ọdún 2019 ní Gold Kolawole di àwáti ni sọ́ọ̀sì ọmọde inú ìjọ náà, lẹ́yin náà ni wọ́n si ti fi ẹsùn ìjínígbé kan pásítọ̀ yii.
Wòlìí náà àti àwọn ọlùkọ́ ilé ìjọsìn ọmọde àti àwọn asọ́nà mẹ́fà ni ọ̀rọ̀ náà kan ti wọ́n si ṣe ìdájọ ẹwọn gbéré fún gbogbo wọ́n.
Lẹ́yìn atótónú lọ́pọ̀lọpọ̀ láti oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni ilé ẹjọ́ ni wọ́n jẹ̀bi ẹsùn ijínígbé àti díde ìwádìí lọ́nà lórí àwọn ẹ̀rí tó wà níwájú ílé ẹjọ́.
Michael Oluronbi

Oríṣun àwòrán, West Midlands Police
Pásítọ̀ ìjọ kan ni Birmingham àti ìyàwọ rẹ̀ ló rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n he nínú oṣù kíní ọdún 2020, lẹ́yìn ti ọkan lára àwọn ti ọkọ́ ti fipa bálòpọ̀ ní ọdún 1989 jáde láti fi ẹsùn kan pásìtọ̀ náà.
Wọ́n ka ẹsùn mẹ́ẹ̀dógún sí i lọ́rùn, eyi ti ìfipábánilòpọ̀ àti ìfìyàjẹni wà lára rẹ̀, iwé ẹsùn náà fi kún un pé, ó ti tó ènìyàn méjìdíláàdọ́rùn tó ti hùwà àìtọ́ yìí sí láàrín ogún ọdún, èyí ti àwọn ọmọ kéékèèké àti àgbà wà nínú wọ́n.
Ní ọ̀pọ ìgbà, ó má ń hu àwọn ìwà yìí lábẹ̀ àsía pé òun fẹ́ wẹ ìwẹ̀ mímọ fún wọ́n (Holy Birth).
Ẹ̀ka ìjọ kérúbù àti Serafu ní ọkunrinn náà nígbà tó wà ni Nàìjíríà.
Oluronbi tó ṣe apoogun gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ tó yàn láàyò jẹ́ ọkan lára ẹni ti ẹsun iyé ènìyàn to fi ipá bálòpọ̀ ga júlọ nínú ẹjọ́ tó ti wá silé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bi adájọ ṣe sọ.
Oluronbi ẹni ọgọ́tà ọdún ni wọ́n mú ní pápákọ ofurufu lásìkò tó n bọ wá sí Naìjìríà.
Mẹ́rin nínú àwọn to fipá bálòpọ̀ náà ló lóyún, tó sì jẹ́ pé, ìyàwó rẹ̀ Juliana ló máa n ṣọ̀nà bi wọ́n ṣe ń ṣẹ́ oyún náà, kódà ọkan nínú àwọn ọmọbinrin náà ló ni òun ti ṣẹ́ oyún tó ìgbà mẹ́fà láti ìgbà ti òun ti wà nílé ìwé girama
Timothy Omotosho

Oríṣun àwòrán, Sowetan/Getty Images
Nínú oṣù kẹwàá ọdún 2018, ajíhìnrere kan Timothy Omotosho ti ìjọ Dominion International Church ni South Africa náà dèrò ẹ̀wọn nítori ẹsùn ifípábánilòpọ̀ to ṣe si ọmọ ìjọ rẹ̀ Cheryl Zondi láti ìgbà tí ó ti wà ni ọmọ ọdún mẹ́rìnlá títí tó fi pé, ọmọ ọdún méjìlélógún.
Láti ǹkan bi ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ló ti wà ni ilé ẹjọ́ tó n dúró de ìgbéjọ lórí ẹsùn tó lé ni mẹ́tàdíláàdọ́rùn tó fi mọ́, fífíni ṣòwò ẹrú, ifipabá awọn obinrin lò pọ̀ nínú ìjọ rẹ̀.
Títí di igba ti a n kọ iroyin yii, ọjọ keje ọsù kẹwàá ọdún 2020, Omotosho sì n wá ọ̀nà láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Sam Kayode
Olùṣírò owó ọmọ Nàìjíríà tó tún ń ṣe iṣẹ́ olùṣọagùtàn lẹ́kọ̀ọ̀kan ni ilẹ ọba (UK) Sam Kayode gba ìdájọ láti lọ sí ẹwọ̀n ọdún mẹ́rìnlá, fún ẹsùn jíjí, mílíọ̀nù mẹ́rin ó le ọwọ́ kan Pọ́ùn nínú oṣù kẹfà ọdún 2016.
Kayode ti owo rẹ̀ lọ́dún kò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta pọ́ùn lọ lọ́dún ni wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n lórí ẹṣùn lílu ọwó ìjó Haberdasher' ilé ìwé ìpínlẹ̀ Aske ni jibiti.
Nínú mílíọ̀nù mẹ́rìn o lé díẹ̀ náà tí ó jí, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rín pọ́ùn péré ní wọ́n rí gbà padà.
Dr Rev King

Oríṣun àwòrán, Google
Chukwu Emeka Ezeugo ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Reverend King ni olùdásílẹ̀ àti alákoso ijọ Christian Praying Assembly (CPA) lọ sẹ́wọ̀n ní ọjọ́ kẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn ọdún 2006 lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ni ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pípa ọmọ ìjọ rẹ̀, Ann Uzoh.
Ó lé ní ọdún mẹ́wàá tí wọ́n fi ṣe ẹjọ́ Rev King, kí, ilé ẹjọ́ gíga ìlú Eko tó dájọ ikú fún lẹ́yìn ti wọ́n ni ó jẹ̀bi ẹsùn ìpànìyàn.
Bótilẹ jẹ pé, ilé ẹjọ kòtẹmilọ́rùn náà ni kí wọ́n pa Rev King, titi di àsìkò yìí wọn ko paa. Falana ti kọwé sí ìjọba ìpińlẹ̀ Eko ọdún 2012 pé ki wọn sọ ìdájọ naa di ẹwọn gbére nítori ti gomìnà tó wá nipò lásìkò náà bá tọwọ́ bọ iwe ikú rẹ̀, ó ti lodí sí ofin ẹtọ ọmọniyan.














