LASEMA: Àwa àti panápaná ń ṣiṣẹ́ kára láti dènà ìjàmbá iná

Ajọ oṣiṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ni awọn ti le awọn eniyan kuro nibi ti iṣẹlẹ ọkọ agbepo to danu ti waye ni ilu Eko.
Adari Ajọ LASEMA, Damilola Oke-Osanyintolu lo fi atẹjade naa lede fun awọn eniyan.
Osanyintolu ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Aso-Odo, Badagry ni ipinlẹ Eko ni Ọjọ Iṣẹgun.
- Adájọ́ sọ wòlíì Sotitobire àtàwọn márùn-ún míì sẹ́wọ̀n gbére!
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé iṣẹ́ ń dúró de akẹ́kọ̀ọ́ tó yan iṣẹ́ olùkọ́ láàyò ní fásitì?
- ENDSARS: Ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ ṣè ìrànwọ́ irinṣẹ́ fáwọn ọlọ́pàá- Naira Marley bẹ̀bẹ̀
- Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
Nibayii, awọn oṣiṣẹ pajawiri ti wa nibẹ lati ri wi pe ọkọ naa ko gbina, lẹyin ti wọn le awọn eniyan kuro ni agbegbe naa.

Bakan naa ni wọn rọ awọn eniyan lati maṣe daba lati ma a ko epo bẹntirolu to danu naa, ki ijamba miran ma ba a waye.
'' A tii bẹrẹ si ni gbọn epo naa kuro nibi to da si, ki ijamba ina ma ba a waye.
Agbegbe naa ti a ko jẹ ki awọn eniyan gba kọja, ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni oju ọna naa.''

LASEMA naa wa rọ awọn eniyan lati ṣe suru fun awọn, ki ijamba miran ma ba tun waye ni agbegbe naa.
Bakan naa ni wọn fi lede pe awọn yoo ma fito awọn araalu leti bi o ba ṣe n lọ.

Kí ló mú kí ọkọ̀ kan tó jóná ráùráú lórí afárá Ojuelegba?
Ọkọ kan ti jona rauru lori afara Ojuelegba nilu Eko.
Iṣẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ Abameta ko mu ẹmi kankan lọ ṣugbọn o ṣe idiwọ fun lilọ bibọ ọkọ lori afara naa.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ninu atẹjade kan ti ọga agba ileesẹ pajawiri nilu Eko LASEMA, Olufemi Osanyintolu fi sọwọ si BBC, awọn eleto aabo ati panapana ni wọn jijọ pa ina to jo ọkọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ẹ̀bùn àti owó tí àwọn olùkópa ti jẹ lórí ètò BBNaija season 5
- Kíni 'Ẹ̀lẹ̀ daddy' Olorì Abbey Adeyemi ṣe tí ojú òpó ayélujára Instagram rẹ̀ fi ń yeruku lálá?
- Ìkébé mi tóbí ju ohun tí mo lè dọwọ́ bò lọ, n kìí fí ṣakọ- Nkechi Blessing
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ má ṣáì lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ Ajé, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà tako ìyanṣẹ́lódì
- Ọgbọ́n àti kówójẹ n'ìgbèsẹ̀ ìjọba láti ná $1.95bn sórí reluwé làti Kano sí Niger Republic- PDP
Osanyintolu ṣalaye pe awọn ti lo irinsẹ agbe ọkọ lati fi gbe ajoku ọkọ naa kuro ti lilọ bibọ ọkọ si ti n lọ geere.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ìbúgbàmù gbogbo ìgbà nílù ú Èkó, kí ló ń ṣokùnfà rẹ̀?
Bi ajalu ba waye ni igba akọkọ, a le sọ pe amuwa Ọlọrun nii ṣe.
Amọ to ba ti wa di nkan to n ṣẹlẹ lemọlemọ, kini ka ti ṣe eyi si?

Oríṣun àwòrán, TWITTER/LASEMA
Ibeere re to gbẹnu awọn ọmọ Naijiria paapa julọ awọn olugbe ilu Eko lori iṣẹlẹ ibugbamu to n waye leralera.
Niwọn igba ti a ko ba ti ribi le dahun ibeere yi lẹkunrẹrẹ, BBC Yoruba yoo gbiyanju lati gbe akọsilẹ jade nipa iye igba tawọn ibugbamu waye ni Eko lọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/LASEMA
Isẹlẹ Ibugbamu gaasi ni Abule Ado
Ọjọ kẹẹdọgun ọsu kẹta ọdun yii jẹ ọjọ manigbagbe fun awọ́n olugbe adugbo Abule Ado nibi ti iṣẹlẹ ibugbamu ọpa gaasi ti ṣẹlẹ niluu Eko.
Awọn eeyan marundinlọgbọn lo farapa ninu ijamba ọhun.
Ninu iṣẹlẹ taa n wi yi, o kere tan eeyan mẹtadinlogun lo padanu ẹmi wọn.
Bẹẹ naa ni ọpọ ile ati dukia farakasa iṣẹlẹ yi ti ọp si di alainile lori.

Oríṣun àwòrán, @followlasema
Ọjọ Kẹtadinlọgbọn Osu Kẹrin, Iṣẹlẹ ibugbamu ile epo NNPC
Adugbo Yaya Abatan ni Ogba nilu Eko ti oun naa wa labẹ ijọba ibilẹ Ifako Ijaiye ni ibugbamu taa n sọ yi ti waye.
Adugbo yi jẹ ibi tawọn eeyan pọ si ti aaye tawọn kan ti n ta ọkọ si farako pupọ ninu ibugbamu yi.

Oríṣun àwòrán, LASEMA/ TWITTER
Bi eeyan ba jẹ ori ahun, to ba ri iru ijamba to waye nibẹ, yoo kanu awọn eeyan.
Ohun to jẹ idunnu ni pe kii ṣe igba tawọn eeyan pọ nita nitori Covid-19. Bibẹ kọ, ọtọ lohun taa baa maa sọ.
Oṣu Kẹjọ 2020, eeyan kan ku ni Alakia
Ibugbamu gaasi naa ni eleyi to waye ni ibudo iwọkọ Alakia ni orile Iganm,u nilu Eko.
Awọn eeyan mẹrin farapa ninu iṣẹlẹ yi.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/LASEMA
Iṣẹlẹ to waye laipẹ yi ni Iju Ishaga
Ọjọ buruku ẹsu gbomimu ni Ọjọru ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹsan jẹ fun awọn eniyan agbegbe Balogun, Iju Ishaga nipinlẹ Eko.
Lọjọ yi, ọkọ nla to n gbe afẹfẹ gaasi gbina to si jo ile mẹtalelogun, ọja, ọkọ marundinlogun, ti eniyan ọgbọn si farapa ninu iṣẹlẹ naa.
Ajọ Lasema loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni awọn ọkọ nla to gbina naa gbe afẹfẹ gaasi wa si agbegbe naa ni ki o to gbina.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ki lara ilu le ṣe?
Loore koore ni awọn ajọ pajawiri n kilọ pe ki awọn eeyan sọrọ tita afẹfẹ gaasi ni itosi ibi tawọn eeyan n gbe.
Nilu Eko to ṣe pe ọpọ eeyan lo n lo afẹfẹ gaasi yi fun idana ati iṣowo, o di dandan ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣada lọna ati dẹkun ibugbamu ni gbogbo igba.
Ni igba ti ibugbamu ti Abule Ado waye, alaga ijọba ibilẹ Ifakọ Ijaiye to fi mọ awọn ọmọ ile aṣofin to n ṣoju agbegbe naa mẹnu ba fifi ofin lelẹ eyi ti yoo kọdi tita afẹfẹ gaasi letile.
Titi di ba ti ṣe n sọrọ yi, ofin naa ko ti di amuṣẹ.
- Wo iye ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àtàwọn ọmọ Nàìjíríà ti ṣèwọ́de lórí àfikún owó epo bẹntírò
- Èkúté tó sàwárí bọ́mbù ilẹ̀ gbàmi ẹ̀ye wúrà fún iṣẹ́ takuntakun
- Ẹ gbó òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa bàbá ìsàlẹ̀...
- Àwọn tó fẹ́ kí ọba máa ta ilẹ̀ ilú ló fẹ́ yọ Oluwo lóyè- Ẹgbẹ̀ Baálẹ̀ Iwo.
- Nǹkan yan, àwọn aṣẹ́wó fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwó epo ní Nàìjíríà















