BBNaija: Laycon, Nengi, Dorathy, Neo àti Vee ti jẹ ẹ̀bùn rẹpẹtẹ lórí ètò Big Brother Season 5

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Awọn ololufẹ ato ori amohunmaworan, BBNaija 2020, ti n foju sọna fun ẹni ti yoo gba miliọnu marunlelọgọrin, to jẹ ẹbun ati owo, laarin awọn olukopa marun to kẹhin sori eto naa.
Ọjọ Aiku ni eto naa yoo wa sopin.
Ṣugbọn, awọn olukopa naa ti n jẹ ẹbun owo ati awọn ẹbun nla miran ṣaaju asiko yii.
Awọn kan lara wọn ti jẹ ẹbun irinajo igbafẹ, jijẹ aṣoju fun awọn ileeṣẹ to ṣe onigbọwọ eto naa.
Awọn kan lara wọn ti jẹ to miliọnu marun Naira.
Nitori naa ni BBC Yoruba ṣe ṣe akojọpọ ẹbun ti awọn olukopa lori eto naa ti jẹ.
Nengi

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Pupọ ninu awọn idije to waye lori eto naa ni Nengi ti jẹ ẹbun.
O si ti gba to owo to le ni miliọnu marun-un, N5,328,000.
Yatọ si eyi, o tun ti jẹ ẹbun ounjẹ fun oṣu mẹta, eroja fun inu ile fun ọdun kan, paali eroja iṣaraloge, ọ̀dà, irinajo si ilu Abuja ati orilẹ-ede Scotland, ati Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest.
O tun jẹ owo Bitcoin to to ẹẹdẹgblta Dọla, ati aṣoju ileeṣẹ.
Laycon

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Laycon, ti ọpọ gbagbọ pe oun ni yoo jawe olubori ninu eto Big Brother Naija fun ọdun 2020, naa ti jẹ ọpọlọpọ ẹbun nibi awọn idije to waye.
Owo to ti jẹ ti le ni miliọnu marun-un Naira, N5,031,000.
Bakan naa lo ti jẹ ẹbun lati polowo ọja, eroja iṣaraloge, ounjẹ ọfẹ, ohun elo inu ile, aṣoju ileeṣẹ, irinajo si Scotland, ati ẹẹdẹgblta Dọla owo Bitcoin.
Dorathy

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Dorathy, to jẹ gbaju-gbaja lori eto naa, ti ọpọ si sọ pe o konimọra, ti jẹ ẹbun owo to to miliọnu mẹrin Naira, N3,926,000.
Ko tan sibẹ o, o tun jẹ ẹbun foonu, ọda, eroja fun inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, ati ẹẹdẹgblta Dọla owo Bitcoin.
Neo

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Neo naa ko kawọ gbera lori eto Big Brother Naija Lockdown.
Oun naa ti jẹ ẹbun owo to le ni miliọnu mẹta Naira, N3,572,000.
Bakan naa lo jẹ ẹbun ohun elo inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.
Vee

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Vee gan-an ko ni i ṣanwọ ofo pada sile lẹyin eto BBNaija. Oun naa raaye jẹ ẹbun miliọnu meji aabọ Naira.
O tun jẹ ẹbun ohun elo inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, irinajo si orilẹ-ede Scotland, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.
Wo nkan ti awọn olukopa to ti já kuro lori eto naa jẹ
Triky tee
- O jẹ N3,359,000
- Ohun elo inu ile
- Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest
- Ọ̀dà
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Ozo
- O jẹ N2,780,000 gẹgẹ bi ẹbun owo
- Ọkọ ayọkẹlẹ
- Irinajo silu Abuja
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
- Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest
Prince
- Oun naa jẹ N2,570,000
- Ohun elo inu ile
- Irinajo silu Abuja
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
- Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest
Kiddwaya
- O jẹ ẹbun owo: N1,720,000
- Foonu tuntun
- Ọ̀dà
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Wathoni
- O jẹ ẹbun owo: N1,250,000
- Eroja iṣaraloge
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Brighto
- O jẹ ẹbun owo: N970,000
- Ọ̀dà
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Tolanibaj
- O jẹ ẹbun owo: N825,000
- Irinajo silu Abuja
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Praise
- O jẹ ẹbun owo: N770,000
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Lucy
- O jẹ ẹbun owo: N570,000
- Ọ̀dà
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Kaisha
- O jẹ ẹbun owo: N570,000
- Ọ̀dà
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Tochi
- O jẹ ẹbun owo: N220,000
- Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
Eric
Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin














