Sex workers strike: Àwọn aṣẹ́wó kílọ̀ fún Buhari kó dá'wó epo padà, bíbẹ́ẹ̀kọ̀, ìyanṣẹ́lódì ló kù

Laarin ọpọlọpọ eeyan lagbaye, iṣẹ aṣẹwo ni wọn mọ gẹgẹ bi iṣẹ to dagba julọ lagbaye.
O dabi eyi gan lo mu ki awọn olowo nọbi lorilẹede Naijiria, o gbe ohun soke lorilẹede Naijiria pe awọn igbesẹ ijọba apapọ n ni iṣẹ awọn naa lara gẹgẹ bi 'oṣiṣẹ'
Awọn olowo nọbi gẹgẹ bi ọpọ ti maa n pe awọn aṣẹwo nilẹ Yoruba naa ti ke gbajare sita pe igbesẹ afikun owo epo ati owo ina ti ijọba apapọ gbe laipẹ yii kii ṣe eyi to ba awọn lara mu rara ati pe ki ijsba apapọ tete daa pada bi owo baba ijẹbu nikan lo lee mu ki awọn pẹlu maa gbe owo ori nọbi awọn soke.
- Ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí lé gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi kúrò ní APC
- Eèyàn 174,574 ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ìrànwọ́ ìjọba fáwọ̀n olókoòwò kéékèèké- Ìjọba Nàìjíríà
- Kò sí iléẹjọ́ tó le dá wa dúró, ìyanṣẹ́lódì yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé - NLC
- Oúnjẹ́ aṣaralóòre nìkan kò tó ò tí o bá n gbèèrò láti lóyún tàbí tí ó bá lóyún
Bakan naa ni wọn ṣeleri pe iyanṣẹlodi wa lara irinṣẹ ti awọn yoo lo lati fi ẹhonu awọn han lori awọn igbesẹ ijọba naa.
Awọn olowo nọbi naa labẹ aṣia ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Self Made Women SMW, ṣalaye lati ẹnu alaga wọn ni ipinlẹ Anambra, arabinrin Uto Nwanyi fi ẹsun kan ijọba apapọ pe ko nifẹ araalu rara ati pe inira ẹkunwo naa yoo ba awọn finra pupọ nitori pe yoo pa iye awọn to n na ohun ti wọn n ta wo.
"A ṣẹṣẹ ti ilu Abuja nibi ti a ti ṣe ipade pẹlu aarẹ apapọ ẹgbẹ wa lorilẹede Naijiria tan ni lori ọrọ ẹkunwo naa. Ki ni iṣoro ijọba wa gan? A ṣẹṣẹ kuro labẹ wahala ajakalẹ arun corona pẹlu awọn igbele gbogbo. Atun ṣẹṣẹ wọ inu oṣu ba-ba-ba ni ti a n lero pe a o tun maa pa ṣenji diẹdiẹ ni ijọba ba tun ni afikun owo ina ati epo lo kan, ṣe wọn fẹ pa wa ni?
- Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn pa ènìyàn méjì
- Eèyàn 174,574 ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ìrànwọ́ ìjọba fáwọ̀n olókoòwò kéékèèké- Ìjọba Nàìjíríà
- Àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí, lọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
- Kò sí iléẹjọ́ tó le dá wa dúró, ìyanṣẹ́lódì yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé - NLC
- Ẹ gbó òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa bàbá ìsàlẹ̀...
O fi kun un pe bi iyanṣẹlodi awọn ko ba tu irun kan lara ijọba lori dida owo epo ati ina naa pada si bo ṣe wa tẹlẹ ri, a jẹ pe awọn yoo fi ida igba ninu ọgọrun un kun owo ori ọja ti awọn naa n ta ni o.
O fi kun un pe ṣaaju asiko yii ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta naira lawọn n gba fun ibalopọ ọlọwọ kukuru Short time ti awọn si n gba ẹgbẹrun marun un fun di ilẹ mọ kẹlẹlẹ daybraek.
Amọṣa, pẹlu bi ajakalẹ arun coronavirus ṣe kan ọrọ aje gbogbo aye, awọn ti jaa walẹ si ẹgbẹrun kan ati ẹgbẹrun mẹrin tabi mẹrin abọ.
- Wo ọ̀nà tí o fi lè dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ COVID-19 níléèwé
- Iléẹjọ́ ní kí Yakubu lọ gé oko àgọ́ ọlọ́pàá fọ́jọ́ méjì lẹ́yìn tó jí fóònù N8,700
- Ẹ yé parọ́ kiri! Orílẹ̀-èdè Amẹrika kò ṣọ́ wọlé-wọ̀de mi àti ìdílé mi- Atiku fèsì
- Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ, epò, iná ọ̀ba ti sọ owó oṣù N30,000 da N9 nitórí náà kò ní sí ọjà, epo, iléèwòsàn láti Ọjọ́ Ajé - NLC
- Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa Da Rocha? Olówó yalumọ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, dailypost.ng
















