Wo ewu tó rọ̀ mọ́ tí o kò bá bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ́ aṣaralóòre lẹ́yìn ti oyún ti dúró sí ọ lára

Oríṣun àwòrán, SPL
Oúnjẹ́ aṣaralóòre nìkan kò tó ò tí o bá n gbèèrò láti lóyún tàbí tí ó bá lóyún
Ko jẹ tuntun lati gbọ ki awọn eeyan o ma a gba alaboyun ni imọran pe ki wọn o ma a jẹun daadaa nitori ki wọn o le bi ọmọ ti ilera ara rẹ pé.
Koda, oriṣiriṣi ounjẹ ni awọn obinrin miran ti ẹ maa n jẹ lasiko ti wọn ba loyun nitori eyi.
Ṣugbọn, njẹ ẹ mọ pe bi ounjẹ jijẹ ninu oyun ṣe ṣe pataki si, naa ni iru ounjẹ ti obinrin ba n jẹ ko to o loyun ṣe pataki, lati le ran an lọwọ fun iloyu, ati fun ọmọ to ba bi.
Oriṣiriṣi iwadii lo ti fihan pe iru ounjẹ ti obinrin ba n jẹ ko to o loyun ṣeeṣe ko ni ipa ninu bi ọmọ rẹ yoo sẹ tobi si, tabi ko bi ọmọ lai pe ọjọ.
Awọn ọmọ ti wọn ba bi laipe ọjọ wa ninu ewu iku nigba ti wọn wa ni ìkókó.
Gẹgẹ bi onimọ nipa iloyun ati ibimọ obinrin, Ọjọgbọn Adetunji Adeniji, lati Fasiti Ladoke Akintola, nilu Ogbomoso, ṣe sọ fun iwe iroyin Tribune, , bi obinrin ba ṣe tin-in-rin tabi sanra si naa ma n ni ipa lara rẹ ati oyun ọmọ to ba ni.
Wọn ni ti obinrin ba tin-in-rin ju bi o ṣe yẹ lọ, o le bi ọmọ ti ko tobi, ti oṣu rẹ ko pe, tabi ki ọmọ naa o ma a ni gìrì ni ìkókó.
Bakan naa ni wọn sọ pe jijẹ ounjẹ aṣaraloore naa ni ipa to n ko ninu idena awọn aleebu to le fẹ ẹ ba ọmọ tuntun.
Fun apẹẹrẹ, ti eroja folic acid ko ba to nkan ni agọ ara obinrin to loyu, ọmọ inu rẹ wa ninu ewu lati ni aisan spinal bifida - ki ọpọlọ ati ọpa ẹyin ko ma dagba daada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Adeniji tun sọ pe o lewu ti iya ba bẹrẹ si ni jẹ ounjẹ aṣaraloore lẹyin to ti loyun, nitori pe laarin oṣu mẹta akọkọ ni oyun ina ti ma n ni gbogbo nkan to yẹ.
Ẹwẹ, o ni idi to tun fi ṣe pataki lati ma a jẹ ounjẹ aṣaraloore ki oyun to o waye ni pe, ọpọ obinrin ni kii tete mọ pe awọn ti loyun, ni ọsẹ mẹjọ akọkọ, to si jẹ pe ko si atunṣe fun kudiẹkudiẹ to ba ti waye lasiko naa mọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe nitori naa lo ṣe yẹ ki awọn ileewosan ma a ṣe idanilẹkọ ati itọju fun awọn obinrin ki wọn o to loyun, bi wọn ṣe ma n ṣe fun awọn alaboyun.
Ni eero ti onimọ nipa ounjẹ ẹdá, lati Fasiti ilu Ibadan, ti oun naa ba Tribune sọrọ, Ọmọwe Oluwaseun Ariyo, sọ pe o dara ki obinrin bẹrẹ si ni lo awọn oogun to le fun un ni eroja folic acid ati iron, lati igba to ba ti balaga, nitori iṣoro aito ẹjẹ to wọpọ ni awọn orilẹ-ede kan, ti ko yọ Naijiria silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọwọlọwọ, ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, sọ pe ki ipese eroja iron ati folic acid wa fun awọn ọmọbinrin to ti balaga, paapa ni awọn orilẹ-ede ti aito ẹjẹ ti wọpọ to ìdá ogoji.
Ti ẹjẹ ko ba pọ to lara obinrin, o le ṣe akoba fun ọmọ inu obinrin naa ninu oyun - bibi ọmọ naa laipe ọjọ, ki ọmọ naa kere ju boṣe yẹ lọ, irẹwẹsi ọkan fun iya , tabi iku fun ọmọ naa ṣaaju tabi lẹyin ti wọn ba bi i.
Ọmọwe Ariyo sọ bakan naa pe ounjẹ jijẹ nikan ko to o. O ni ere idaraya , yiyago fun ọti lile, siga tabi awọn nkan oloro miran, naa ṣe koko fun oyun ti ko ni i mu wahala kankan dani.
- WASSCE: Ìpínlẹ̀ Delta fòfin de olùkọ́ 41 tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò
- Wọ́n ti yìnbọn pa ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó ń jà sí ogún ilẹ̀ bàbá rẹ̀
- Ẹgbẹ́ NULGE Oyo dìbò yan olóyè ẹgbẹ́ tuntun èyí tó tako àṣẹ iléẹjọ́
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú sọ orúkọ Tolulope Arotile di mánigbàgbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel


















