Adesuwa Etomi Wellington ní ìranù pátápátá ni ọbẹ̀ gbẹ̀gìrì

Oríṣun àwòrán, others
Gbajugbaja oṣere sinima, Adeṣẹwa Etomi Wellignton to tun jẹ iyawo fun ilumọọka akọrin takasufe, BankyW ti bu ẹnu atẹ lu ọbẹ gbẹgiri.
Ninu ọrọ kan to sọ loju opo twitter rẹ, Adeṣẹwa ni oun ti pinnu lọkan oun pe iranu patapata gbaa ni ọbẹ gbẹgiri ti ọpọlọpọ ọmọ Yoruba kundun lati maa fi jẹ Amala.
- Eruku ẹjọ́ tún sọ lórí ìgbéyàwó Toyin Abraham àti Adeniyi Johnson tó forí ṣánpọ́n
- Wo bí o ṣe lè se ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ yìí àti àwọn oúnjẹ Yorùbá aládùn míràn
- Ẹ wo iye t'óúnjẹ dà báyìí lọ́jà lẹ́yìn tí ìjọba ti ibodè

- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
O ni awọn ọrẹ oun lo fi tipatipa mu oun jẹ ọbẹ Amala oun pẹlu gbẹgiri; ṣugbọn nisinyii ti oun ti dagba, to ojuubọ, oun ti wa rii pe 'amala pẹlu ọbẹ ewedu ati ọbẹ ata dindin ni ọkan mi gbadun julọ lati fi jẹ amala'.
Gbẹgiri jẹ ọbẹ kan pataki ti awọn ọmọ Yoruba kii fi ṣere bi wọn ba fẹ jẹ Amala.
Gbajugbaja oṣere sinima naa ni abupọ ọbẹ gbẹgiri ati ewedu ti ọpọ n pe ni abula lawọn agbegbe bii Ibadan, Ọyọ, Osogbo ati bẹẹbẹẹ ls bi wọn ba fẹ jẹ amala ni ajẹgbadun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Amọṣa, ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni wọn ti ya bo oṣere sinima yii lori ayelujara, paapaajulọ loju opo Twitter rẹ ti wọn si ni ọrọ to sọ nipa ọbẹ gbẹgiri jina si ootọ.
Ni iwoye tirẹ, Theophilous-Truth-hurts(omo iya calabar) @theonce001 salaye pe Amala ti Adesuwa n sọ pe oun gbadun ju amala pẹlu gbẹgiri kii ṣe amala gidi ti gbogbo aye mọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ni tirẹ, Ọgbẹni ni ẹkọ ẹlẹkọ ni ẹgba ẹlẹgba ati pe ki Adesuwa dẹkun sisọ ọrọ odi si amala nitori oun gẹgẹ bi ọmọ Ogbomoṣọ ko ni tẹwọ gba irufẹ ọrọ odi bẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Bakan naa ni Ṣèyí Pàtàkì, @seyi_ro naa ko fi oju rere wo ọrọ ti Adesuwa sọ yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bẹẹ lawọn miran n juwe agbegbe ti awọn ti jẹ ọbẹ gbẹgiri ati amala ti ko lẹgbẹ kaakiri.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5

End of X post, 6

End of X post, 7

End of X post, 8

End of X post, 9

End of X post, 10
Bakan naa la ri awọn ọm naijiria miran ti wn kin Adesuwa lẹyin pe lootọ ni ọbẹ gbẹgiri kii ṣe ọbẹ to ṣee pọnle.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 11

End of X post, 12

End of X post, 13

End of X post, 14

End of X post, 15
Yoruba Foods: Ọ́pọ́ àwọn oúnjẹ wọ̀nyí ló ti ń di ìgbàgbé, táa sì gbọdọ̀ pè padà

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹya Yoruba yaayi, wọn gbafẹ, wọn ni aṣa, ede ati ọpọ ohun ajogunba to jẹ manigbagbe, eyi ti ko ṣee fi ọwọ rọ sẹyin.
Ki awọn oyinbo alawọ funfun to de ni Yoruba ti n ṣe aye, wọn n wọṣọ, wọn n jẹun, ti awọn ounjẹ wọn kii si ṣe aṣadanu.
Awọn ounjẹ Yoruba gbajumọ pupọ, ti awọn ẹya miran gan ṣi kundun lati maa jẹ ounjẹ yii nitori adun rẹ ati bo ṣe n ṣe ara loore.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Òkè Idanre rèé tí odidi ìlú kan ló ń gbé lórí ẹ̀
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
Fun apẹẹrẹ, amala, ẹba ati iyan jẹ ounjẹ abalaye iran Yoruba ṣugbọn o ti di itẹwọgba bayii lọdọ awọn ẹya miran lorilẹede Naijiria.
Ṣugbọn fun iyalẹnu ọpọ eeyan, diẹ lara awọn ounjẹ ati ọbẹ abalaye wa ti n lọ sokun igbagbe, idi si ree to fi yẹ ka pe akiyesi wa sawọn ounjẹ naa, ki wọn maa baa di igbagbe patapata.
Awọn ounjẹ ati ọbẹ manigbagbe nilẹ Yoruba:
Ẹwa Agọnyin:
Arimalelọ ni ẹwa Agọnyin, awopadasẹyin si ni pẹlu, paapa ọbẹ alata ti wọn maa n bu le e lori.

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹwa Agọnyin yatọ si ẹwa alasepọ to wọpọ, eyi ti wọn maa n ro epo ati ata papọ, ṣugbọn ọtọ la n din ata ori ẹwa Agọnyin.
Ẹwa pupa ni wọn maa fi n se ẹwa yii, ti wọn si maa n din ata rẹ, ti yoo gbẹ titi yoo fi din di dudu ki wọn to bu u le ẹwa naa lori.
Ikọkọrẹ:
Isu Ewura ni a fi n se Ikọkọrẹ, ẹlẹmi meje ni, tori ọpọ eroja ti wọn fi n se e, to si wọpọ laarin awọn ẹya Ijẹbu.

Oríṣun àwòrán, Others
Lara awọn eroja taa nilo taa ba fẹ se Ikọkọrẹ ni Isu ewura, alubọsa, epo pupa, awọn eroja amuọbẹdun, ẹja gbigbẹ, pọnmọ, inu ẹran ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ko si ẹni ti o foju kan Ikọkọrẹ ti ebi ko ni pa lati jẹ nitori ẹlẹmi ọgbọn ni ounjẹ ọhun.
Mọin-mọin ẹlẹmi meje:
Asọdun ni pe ounjẹ kan ni ẹmi meje amọ taa ba se mọin-mọin naa, amọ pe ko si irọ ninu orukọ ti wọn n pe.

Oríṣun àwòrán, Others
Mọin-mọin tabi ọọlẹ ni wọn n fi ẹwa se, pẹlu eroja ata, ewe, epo abi ororo, ti wọn si maa n fi ẹja, ede, ẹyin ati ẹran wẹwẹ sinu ounjẹ yii.
Owo nla lo pa mọin-mọin ẹlẹmi meje tori ko wa fun ẹniti ko lowo lọwọ tori ọpọ eroja to nilo, to si n se ara loore pupọ pẹlu.
Egbo ati Ẹwa:
Ẹgbo ati ẹwa jẹ ounjẹ abalaye to ti n lọ sokun igbagbe bayii, to si yẹ ka pe akiyesi wa si.

Oríṣun àwòrán, Others
Agbado gbigbẹ ti wọn ti bo, ni wọn fi n ṣe egbo, wọn yoo fẹ idọti ara rẹ kuro, ki wọn to da sori ina lati see, titi ti yoo fi rọ
Lẹyin eyi ni wọn yoo wa bu ẹwa sise le lori, eyiun ẹwa fifọ bii ẹwa Aganyin, ti wọn yoo si bu ata dindin le lori pẹlu.
Adun ẹwa Aganyin ko se fẹnu sọ nitori onibeji to jẹ, to si n fun ni lokun, agbara ati eroja asara loore.
Irẹsi Ọfada:
Bi o tilẹ jẹ pe awọn oyinbo alawọ funfun lo ko irẹsi wa silẹ yii, sibẹ, awa naa ni irẹsi tiwa n tiwa to wọpọ laarin wa ni bii adọọta ọdun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Others
Irẹsi Ọfada jẹ eyi to lee wu lorilẹede yii, yatọ sawọn ẹya irẹsi miran, to si ni adun ti ko ni afiwe.
Lootọ ni irẹsi ọfada ni okuta, ams ta ba fi ara balẹ see, a gbadun rẹ ti adun rẹ ko si ni tete di ohun igbagbe.
Ọbẹ ata dindin pẹlu inu ẹran, ede, pọnmọ, inu ẹran ati iru lo mu ki ọbẹ ọfada yatọ si awọn ọbẹ ounjẹ miran, arimalelọ si ni pẹlu.
Iyan ati ẹfọ riro:
Yoruba ni iyan ni ounjẹ, ọka ni oogun, eyi to n sọ bi ounjẹ naa ti se pataki si lawujọ wa.

Oríṣun àwòrán, Others
Alejo ti wọn ba gun iyan fun, ọba ni, nitori adun rẹ, paapa ta ba fi adiẹ se ọbẹ ata taa fi jẹ.
Isu ti wọn se lori ina, ti wọn si gun lodo lẹyin ti isu jinna tan la n pe ni iyan, ọbẹ ẹfọ riro si la saba maa n fi jẹ.
Orisirisi ẹfọ riro lo wa bii sọkọ, tẹtẹ, igbo, ati bẹbẹ bẹẹ lọ ta lee fi jẹ iyan, ti a si fi awọn eroja ẹlẹmi meje bii pọnmọ, ede, ẹja gbigbẹ, panla, igbin ati bẹẹ bẹẹ lọ se.
Akara olororo tabi Sẹẹkẹ ati akara elepo ta mọ si Kengbe:
Ẹwa ti a ti lọ kun pẹlu awọn eroja bii ọpọ alubọsa ati asa, ta wa din ninu ororo tabi epo pupa la n pe ni akara.

Oríṣun àwòrán, Others
Akara kọja nkan ipanu nitori ounjẹ asaraloore gidi ni, to si tun maa n mu ki ara fuyẹ.
A lee fi epo tabi ororo din akara, o si wa lọwọ ta ba se fẹ si.
Akara ba ba fi ororo din la n pe ni Sẹẹkẹ, aye ode oni si lo ti wọpọ nigbati awọn oyinbo n se ororo.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ laye atijọ, akara taa fi epo din, ta n pe ni kengbe lo wọpọ, ki sẹẹkẹ to de.
A le fi ede ati ẹja sinu akara ta fẹ din lati mu ko ladun, bakan naa si la lee fi ata wẹwẹ sinu rẹ ko lee ta lẹnu.
Asaro elede abi Ẹbẹ:
Eroja ounjẹ miran ti awọn ọdọ ode iwoyi ko saba kundun, to si ti n di manigbagbe lọ ni Asaro abi Ẹbẹ jẹ.
Isu taa se pẹlu ata ati epo pupa ni a n pe ni asaro, to si tun lee ni eroja amounjẹ dun bii ede, ẹjọ, inu ẹran ati bẹẹ bẹẹ lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Bi isu ba ti jinna tan, la fọ si wẹwẹ, ti a si fi ata ati epo si eyi to mu ki wọn maa pe ni asaro elede abi elepo rẹbẹ-rẹbẹ.
Asaro rọrun lati jẹ ju isu lasan lọ nitori ọpọ eroja asaraloore miran ta se pẹlu rẹ.
Ekuru Aro ati Ekuru funfun:
A lee pe Ekuru ni onibeji nitori Ekuru aro ati funfun maa n lọ papọ ni.
Ẹwa taa ti bo, ta si fi ẹrọ lọ lai fi ata tabi epo si la n pe ni ekuru.

Oríṣun àwòrán, Others
Ekuru ta ba fi kaun diẹ sinu rẹ la n pe ni aro, tori kaun inu rẹ yoo jẹ ko dudu bii aro, ekuru ti a ko si fi kaun si ni wsn n pe ni ekuru funfun.
A maa n jẹ ekuru mejeeji yii papọ ni pẹlu ata dindin bii ata ẹwa aganyin, ti ata rẹ ọhun naa si maa n ni awọn eroja ẹlẹmi pupọ bii ede, ẹjọ, ẹran wẹwẹ ati inu ẹran.

Oríṣun àwòrán, Others
Yoruba gbagbọ pe ekuru ni ounjẹ ibeji, ti wọn si maa n se fun wọn.