Border closure: Ẹ wo iye t'óúnjẹ dà báyìí lọ́jà lẹ́yìn tí ìjọba ti ibodè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Niṣe lawọn ọmọ Naijiria n pariwo lori ọwọn gogo ounjẹ nitori ibode ori ilẹ ti ijọba apapọ ti pa lati oṣu kẹjọ.
Ounjẹ bi irẹsi, iṣu, ẹran adiẹ tutu ati ohun elo ọbẹ bi timọti lo ti gbowo lori bayii.
Ẹwẹ, ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni lootọ ni pe ibode ti awọn ti lo fa ki owo ọja o gbe pẹẹli soke si Ibodè tí a tì ló fa ọ̀wọ́ngógó owó ọjà- Ìjọba Naijiria.
Minisita fun eto isuna orilẹ-ede Naijiria, Abilekọ Zainab Ahmed lo sọ bẹẹ lẹyin ipade igbimọ alasẹ ti ijọba apapọ, Federal Executive Council ni ilu Abuja.
Eyi ni atupalẹ iye owo ti wọn n ta awọn ọunjẹ kan ki ijọba to ti bọda ati lasiko yii ti wọn ti ṣi ibode.
Irẹsi
Awọn eeyan maa n ra baagi ireṣi kan ki ijọba to ti ibode ni bi ẹgbẹrun mẹtala naira si mẹrindinlogun (eyi nii ṣe pẹlu ti irẹsi naa ba ṣe mọ to ati ibi ti wọn ti n ko o wa).
Ṣugbọn iresi ti gbowo lori lẹyin ti ijọba ti ibode tan, baagi irẹsi kan ti di ẹgbẹrun lọna ogun naira si ẹgbẹrun lọna mejidinlọgbọn bayii, koda awọn irufẹ irẹsi mii maa ju bẹẹ lọ.
Ohun tawọn olutaja n sọ ni pe awọn ko tilẹ ri irẹsi ti wọn n gbin ni Naijiria ra, eyi jẹ ko nira lati mọ iye ti wọn ta gan an.

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹran adiẹ
Ki ijọba to ti ibode pa fun apẹrẹ niluu Eko, apo mẹfa naira ni wọn maa n ta ẹran adiẹ (chicken) tutu kilo kan.
Ṣugbọn ni bayii, kilo ẹran adiẹ tutu kan ti di apo mẹjọ naira.
Koda ẹni to ba fẹ ra Tọki gbọdọ mu apo mẹjọ naira lọwọ ko to le ri kilo Tọki kan ra bayii.
Tomato
Tomato naa ko gbẹyin ninu awọn ounjẹ ati ohun elo to ti gbowo lori lẹyin ti ijọba ti ibode pa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun apẹrẹ, ogoji kilo tomato ti wọn n ta ni ẹgbẹrun un mẹfa aabọ naira lọja Bodija niluu Ibadan ti di ẹgbẹrun un mẹjọ le laadọrin naira.
Ororo
Awọn eeyan maa n ri ororo jala mẹẹdọgbọn ni ẹgbẹrun mẹsan an aabọ naira ki ibode to di titi pa ṣugbọn bayii o gbọdọ ni ẹgbẹrun mọkanla si mẹẹdogun lọwọ koo to le ra ororo to tẹ ẹ lọrun.
Koda awọn kan n ra ororo naa ti gbowo lori, ẹgbẹrun mọkanla din igba naira ni wọn ta a nisinyi.














