Sowore: Ilé aṣòfin Amẹrika ní ìwà ìfìyàjẹni tíjọba Nàíjíríà hù ń kọ àwọn lóminú

Awọn eeyan to n ja fun itusilẹ Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Ile asofin Amẹrika to wa nilu Washinton DC ti koro oju si bijọba Naijiria se n tẹsiwaju lati fi Omoyele Sowore, Jones Abiri ati Kofi Bartels pẹlu Samuel Ogundipẹ si ahamọ ọlọjọ pipẹ.

Bakan naa nile asofin Amẹrika tun fi aidunnu rẹ han si ohun to pe ni iwa titi awọn ileesẹ iroyin ati ayelujara pa ni Naijiria, pẹlu afikun pe igbesẹ ijọba ati tawọn ileesẹ agbofinro rẹ safihan aikọbi ara si ominira araalu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile asofin Amẹrika gbarata bẹẹ ninu iwe ẹhonu kan to kọ ransẹ si ileesẹ asoju ijọba Naijiria pẹlu afikun pe iwa ifiyajẹni ijọba Naijiria ti n kọ ọpọ eeyan lominu, to si n mu ifura lọwọ.

Omoyele Sowore wa nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

"Ijọba ti n kọ eti ikun si ọpọ asẹ ileẹjọ lati tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ, to si tun n lo agbara apapsẹ waa lati tako awọn eeyan to n fi ẹhonu han lawọn agbegbe kan lorilẹede naa, eyi to n kọ wa lominu pupọ, to si jẹ ẹdun ọkan fun wa."

Iwe naa, ti asofin agba nilẹ Amẹrika, Sẹnetọ Robert Menedez ati ọmọ ile asoju sofin kan, Josh Gottheimer dijọ fọwọsi lo tun bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria fun bo se n huwa ọyaju, to si tun ti Sowore atawọn eeyan miran mọle, awọn to sọ pe wọn n sewadi, ti wọn si n sọrọ sita lati tako awọn isoro ti wọn kẹẹfin nidi eto isejọba, to fi mọ iwa ajẹbanu ati aisi eto aabo to peye.

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

"Ọpọ awọn iroyin ti ko fararọ lo ti de etigbọ wa,nipa bi awọn ileesẹ alaabo se n fiya jẹ awọn akọroyin, ti wọn si tun n ti wọn mọle, ti wọn n lo agbara ati iwa ipa lori awọn oluwọde ti ko huwa idaluru ati awọn igbesẹ miran to lee pagi dina ominira sisọ ero ẹni, eyi to n di awọn ọmọ Naijiria lọwọ lati sọ tẹnu wọn gẹgẹ bi ẹtọ ọmọniyan ti gba wọn laaye."

Ile asofin Amẹrika wa n rọ ijọba Naijiria lati ri daju pe o bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan gẹgẹ bo se wa ninu ofin ilẹ wọn fun araalu kọọkan, ki wọn si gbe igbesẹ lati di alaafo to wa laarin wọn ati awọn akọroyin, awọn ọmọ ẹgbẹ oselu alatako, atawọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọẹni.

O fikun pe, ẹtọ araalu kọọkan ni wọn gbọdọ bọwọ fun laisi idunkooko lọdọ ijọba fun igbẹsan, ta si n foju sọna fun ilọsiwaju nidi awsn ohun to se koko ta mẹnuba naa.