Oṣun State: Gómìnà Oyetola ní 167,000 yàrá ìkàwé ni òun kọ́ sí 32 iléẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gboyega Oyetola
Gomina ipinlẹ Oṣun, Gboyega Oyetola ti sọ pe ijọba oun ti mu ileri rẹ ṣẹ lori eto ilera nipinlẹ naa.
Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ sun sọ lati fi sami ọdun kan ti o gori aleefa gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oṣun, ni Oyetola ti fidi ọrọ yii mulẹ.
Oyetola ni oun ṣeleri ni ibẹrẹ ijọba oun pe, oun yoo pese eto ilera to peye fawọn eeyan ipinlẹ naa lọna ti ko ni na wọn lowo pọju.
- Nínú àbá ìṣúná 2020, ìjọba Ọyọ fẹ́ gba 500 òṣìṣẹ́ ìlera pẹ̀lú ọ̀pọ̀ olùkọ́
- Makinde sàbẹ̀wò sí LAUTECH, ó gbé owó ₦500m kalẹ̀ láti tán ìyanṣẹ́lódì àwọn olùkọ́
- Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tó lu akẹẹgbẹ́ wọn ní fásitì FUTA dèrò ilé
- 'Ẹ gbà mí o lọ́wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wa, mi ò lènìyàn, ẹ bá mi wá ọmọ mi rí'!
- 'Kìí ṣe gbogbo ohun tí dókìtà ni kí n má jẹ torí àìsàn jẹjẹrẹ ni mo tẹ̀lé'
- Ǹjẹ́ o nímọ̀ nípa agogo inú ara rẹ?
- Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́
O ni ijọba oun ṣe eleyi nipa agbekalẹ eto ilera fun mutu-muwa eyun-un ni, Osun Health Insurance Scheme (OHIS).
Gomina sọ pe ''ẹgbẹrun un lọna ọgọrin eeyan ti wọn ko rọwọ họri ni wọn ti janfaani eto ilera to peye laisan kọbọ labẹ eto OHIS ni bii ọdun kan sẹyin.''

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetolaileriOluwa
Eto aabo
Gomina Gboyega Oyetọla ni ijọba ti ṣiṣẹ takuntakun lati rii wi pe ipinlẹ Oṣun ṣi wa lara awọn ipinlẹ ti eto aabo wọn muna doko.
Gomina ni ijọba oun pese awọn ohun eelo fun eto aabo ati ọkọ ayẹta pẹlu awọn ohun elo mii fawọn oṣiṣẹ eleto aabo nipinlẹ Oṣun.
Eto ẹkọ
Gomina ipinlẹ Oṣun ni ijọba oun ti kọ yara ikawe mẹtadinlaadọsan an ni ijọba ibilẹ mejilelọgbọn kaakiri ipinlẹ naa.
O fikun ọrọ rẹ pe, awọn akẹkọọ ati olukọ to le lẹgbẹrin ni wọn n jẹ anfaani awọn yara ikawe ọhun.
Oyetola ṣalaye pe ohun to ku fun ijọba oun bayii ni lati mojuto eto ẹkọ imọ ẹrọ eleyi ti yoo pese iṣẹ fawọn araalu.
Iranlọwọ fun araalu
Gomina Oyetola tun ṣalaye pe, ijọba ipinlẹ Oṣun labẹ ijọba oun laarin ọdun kan sẹyin ti ṣeranwọ owo fawọn ọdọ lati lati rii wi pe airiṣẹ ṣe dinku nipinlẹ naa.
Gomina sọ pe, eto ironilagbara ti orukọ rẹ n jẹ Osun Youth Empowerment Scheme (OYES) ni ijọba fi kan si ọpọ araalu.
Gomina ni ijọba oun gba awọn olounjẹ to le ni ẹgbẹrun un meji lati maa gbe ounjẹ kaakiri ile iwe alakọbẹrẹ kaakiri ipinlẹ ọhun, fun eto ounjẹ ti ijọba n fawọn akẹkọọ.
Iṣẹ ọgbin
''Ohun ti ijọba Oṣun fẹ ṣe ni lati sọ iṣẹ agbẹ di iṣẹ to lowo lori eleyi ti yoo wu ọpọ lati maa ṣe,'' Gomina Oyetola woye bẹẹ.
Gomina Oyetola ni ijọba oun ṣetan lati lo iṣẹ agbẹ pese iṣẹ fawọn eeyan ipinlẹ Oṣun.












