LAUTECH Crisis: Makinde ní kí ìpínlẹ̀ Ọyọ gba àkóso fásitì náà ni ọ̀nà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti se abẹwo sile ẹkọ imọ ẹrọ fasiti Ladoke Akintola LAUTECH to wa nilu Ogbomoso ni aarọ ọjọ Isẹgun.
Lasiko abẹwo ọhun ni gomina Makinde gbe miliọnu lna ẹẹdẹgbẹta naira kalẹ lati lee fopin si iyansẹlodi awọn olukọ ile ẹkọ̀ fasiti naa, to si tun se ipade pọ pẹlu awọn eeyan ti ọrọ ileẹkọ naa gberu lọna ati wa ojutu si wahala to n koju ileeẹkọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nigba to n ba ipejọpọ naa sọrọ, gomina Makinde fọwọ gbaya pe oun yoo da si ọrọ̀ naa ki iyansẹlodi naa lee di ohun igbagbe, ti eto ẹkọ kikọ yoo si bẹrẹ lọgan.
Bakan naa lo fi ewe ọmọ mọ awọn osisẹ fasiti LAUTECH leti pe ki wọn dẹkun dida ija silẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Ọsun, to si tun seleri pe ko si osisẹ fasiti naa ti wọn yoo le lẹnu isẹ lai naani ipinlẹ ti wọn ti wa.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
"Mo tun ba awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ osisẹ nile ẹkọ LAUTECH sọrọ lori bi wọn yoo se se amulo owo idoola isoro ti mo gbe kalẹ, ati ọna ti wọn yoo gba fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati wa ọna abayọ titi laelae si awọn ipenija to n koju ileẹkọ naa."

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Bakan naa tun ni Makinde fikun pe, aba ti oun gbe kalẹ lati gba akoso ileẹkọ fasiti LAUTECH labẹ akoso ipinlẹ Ọyọ nikan ni ọna abayọ si ọpọ ohun ti fasiti naa n poungbẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
O tun tẹnumọ pe, "eyi ko tumọ si pe mo fẹ kẹyin si awọn eeyan wa to wa nipinlẹ Ọsun nitori ẹbi kannaa ni wa amọ igbesẹ naa yoo jẹ ọna abayọ ayeraye, nitori ipinlẹ Ọyọ ti gbaradi pẹlu owo lati gbe ẹru sise akoso ileẹkọ fasiti naa gẹgẹ bii eyi to jẹ tirẹ nikan."
Seyi Makinde palẹ̀ ẹ̀gbin Ibadan mọ́ lóru mọ́jú, ó ṣèlérí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin fún ìmọ́tòtó àyíká

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Owurọ kutu Ọjọ Iṣegun ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati ikọ rẹ gba igboro Ibadan lọ lati palẹ awọn idọti to dabi oke nilu Ibadan mọ.
Saaju ni gomina ti pasẹ fun gbogbo awọn eeyan to dipo oselu mu ninu ijọba rẹ ati awọn oludari agba nileesẹ́ ijọba kọọkan lati bọ sigboro ilu Ibadan, ki wọ̀n si ko gbogbo awọn idọti to wa laarin oju popo kuro, ki ayika lee dun wo.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Makinde ko fi ọ̀rọ̀ naa se ti ipo asaaju, funra ara rẹ loun naa bọ si ita gbangba lati mojuto eto naa lẹyin aṣẹ to pa fun awọn oṣisẹ ijọba ati oloselu naa, ti awọn osisẹ fun ile isẹ to n risi imọtoto ayika naa si kọwọrin tẹle Gomina Makinde lati ṣe eto gbalumọ ọhun.
Gomina Seyi Makinde ti kọkọ se ipade lọsan ọjọ aje pẹlu awọn eeyan ti eto ipalẹmọ ẹgbin nipinlẹ Ọyọ gberu ati awọn ọmọ igbimọ alakoso fun ileesẹ to wa fun ipalẹmọ ẹgbin nilu Ibadan.
Koko ipade naa si lo da lori ọna lati wa ojutu si isoro akoso ẹgbin to n ba ilu Ibadan finra, ti Makinde si fọwọ sọya pe oun yoo ri daju pe wọn ko gbogbo awọn ẹgbin to dabi oke nilu Ibadan kuro laipẹ.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
"A ri daju pe a fi ofin to de dida ilẹ kiri laibikita mulẹ nipinlẹ Ọyọ, ta si tun wa ọna abayọ si isoro ẹgbin laarin ọsẹ mẹrin pere si asiko yii.'
Mo wa n rọ awọn eeyan ipinlẹ yii lati fara da pẹlu mi nibayii ti mo n lakaka lati wa ojutu si isoro naa, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu wa lati ri pe ayika wa mọ tonitoni, ti ko si lewu fun gbogbo wa lati gbe."

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Lara awọn eeyan miran to tun tẹle gomina Makinde ni lati oludamọ̀ran rẹ feto aabo, Fatai Owoseni, ti gbogbo wọn si sisẹ loru mju lati ri daju pe ọrọ ẹgbin to fọn kaakiri ilu di afiẹyin, ti eegun fi asọ.
Bẹẹ ba gbagbe, ileesẹ BBC Yoruba naa ti pe akiyesi ijọba ipinlẹ Ọyọ si obitibiti ẹgbin to n se ilu Ibadan lọsọ, ti kọmisana fọrọ ayika naa si fi da wa loju pe laipẹ ni isoro ẹgbin ayika ọhun yoo di ohun igbagbe.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK













