Traffic gridlock: Sanwo-Olu fẹ́ sún ìrìnnà ọkọ̀ àjàgbé kúrò lọ́sàn sí òru l'Eko

Sunkẹrẹ ọkọ ni Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Njẹ o mọ pe o ṣeeṣe ki irinna loju popo ni ọsan di eewọ fun gbogbo awọn ọkọ ajagbe nlanla ni ipinlẹ Eko?

Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti n pariwo lori ọṣẹ ti awọn ọkọ ajagbe, yala eyi to n gbe epo ni tabi awọn ẹru miran, maa n ṣe lawọn oju popo; paapaa julọ ni ipinlẹ Eko.

Eyi gan an fẹẹ lo faa ti gomina ipinlẹ Eko, Babatunde Sanwo-olu fi kede pe laipẹ gbogbo irinna ọkọ to ba jẹ ajagbe ni wọn yoo fi mọọ si alẹ dipo ọsan tabi ojumọmọ.

O ni ijọba ipinlẹ Eko ti n le awọn ọkọ ajagbe kuro lagbegbe Iganmu bayii ki oju ọna lee la fun awọn to fẹ rinrinajo lọ si Apapa.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá

Gomina Sanwo-Olu ni ijọba Eko ti n fi orikori lori awọn ọna lati ṣakoso irinna ọkọ ni ipinlẹ Eko ki wọn si yanju iṣoro bi oju popo ṣe maa n di gadigadi.

Bakan naa lo ṣalaye pe atunṣe awọn oju popo ati oju odo yoo waye pẹlu ki ipinlẹ Eko lee tẹsiwaju gẹgẹ bii aayo awọn oludokowo gbogbo.