'Sẹ́ríkí Fúlàní ní ìpínlẹ̀ Ọṣun ní kò sí ìdí fún àwọn darandaran láti kúrò l'Ọ́ṣun

Daran daran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni opin ọsẹ to kọja ni okiki kan nipa iṣẹlẹ kan eyi to ṣẹ ninu eyi ti ara ti san pa maluu ti ko din ni mẹtadinlogun ninu agbo ẹran darandaran fulani kan ni ilu Iba ni ipinlẹ Ọṣun.

Iṣẹlẹ naani yoo si jẹ ẹkẹta iru ẹ ti yoo maa waye laarin oṣu mẹta ni ilẹ Yoruba.

Amọṣa iroyin to wa jẹyọ lẹyin iṣẹlẹ ti ipinlẹ Ọṣun lo ko awọn eeyan laya soke pe awọn darandaran Fulani kan ti n fi ipinlẹ naa silẹ ni ibẹru-bojo pe ki atunṣẹ ikọlu ara to ti fẹ maa di lemọlemọ lori awọn maluu o ma baa kan awọn pẹlu.

Agbo maluu kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria ti kọkọ gbe iroyin yii pe eyi to ti n da ariyanjiyan silẹ laarin ọpọ titi de ori ayelujara.

Ninu ọrọ to ba BBC news Yoruba sọ lori ẹrs ibanisọrọ, Seriki awọn Fulani ni ipinlẹ Ọsun Alhaji Oluwatoyin Sulaeman ṣalaye pe ko si otitọ ninu iroyin naa.

Daran daran

Oríṣun àwòrán, SIA KAMBOU

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá

Alhaji Oluwatoyin Sulaeman ni lootọ ni ara san pa agbo ẹra arakunrin naa ṣugbọn awọn gbaa gẹgẹ bii iṣẹlẹ amuwa Eledumare eyi ti ko nii ṣe pẹlu wahala tabi edeaiyede laarin awọn darandaran ati awọn ara ilu ti wọn tẹdo sii.

Sẹriki Fulani naa tẹ siwaju pe ọkan awọn darandaran balẹ ni ipinlẹ Ọṣun, wọn ko ni ikayasoke kankan nipa abo ati alaafia awọn ati agbo ẹran wọn.

O wa rọ ijsba ipinlẹ Ọṣun lati dide iranlọwọ fun arakunrin ti adanu naa ṣẹ si nitori pe gbogbo dukia rẹ naa ni ara san pa naa.