Uganda faulty condom: Uganda kó rọ́bà ìdáàbòbò mílíọ̀nù kan kúrò ní ìlú

Oríṣun àwòrán, Marie stopes Uganda
Ile iṣẹ arannilọwọ kan ti kii ṣe ti ijọba ni orilẹ-ede Uganda ti palẹmọ awọn rọba idaabobo wọn kuro nilẹ.
Marie Stopes ti ko awọn rọba to le ni miliọnu kan ti wọn ti kọkọ pin fawọn eeyan Uganda kuro nilẹ.
Ni kete ti wọn kẹfin pe abuku wa lara awọn rọba idaabobo wọnyii ni wọn ti n ni kawọn ti wọn ti pin in fun da a pada.
Iwadii ajọ to n mojuto ilo oogun ni Uganda, iyẹn Uganda National Drug authority fihan pe iho diẹdiẹ wa lara awọn rọba idaabobo ti ileeṣẹ Life Guard ti India ba wọn ṣe.
Ileeṣẹ arannilọwọ Marie Stopes maa n pese ọna idaabobo ara ẹni, ati ifetosọmọbibi fun awọn orilẹ-ede to le ni marundinlogoji ni agbaye ni.
Ajọ iṣọkan agbaye, United Nations ni pe o to ida mẹfa ninu ọgọrun un awọn eniyan orilẹ-ede Uganda lo ni arun kogboogun HIV.
Iwadii miran tun fihan pe ida mọkanla ninu ọgọrun un oyun ti awọn eniyan Uganda n ni lo jẹ eyi to wu wọn lati ni funra wọn lasiko naa.
Loṣooṣu ni Marie Stopes maa n ko rọba idaabobo bii miliọnu kan abọ si meji wọ orilẹ-ede Uganda.
Atẹjade ti wọn fi sita fun BBC ni: Eyi ni igba akọkọ ti a ni lati gba awọn nkan iranlọwọ wa pada nitori abuku kan.
Marie Stopes bẹrẹ si ni gba awọn rọba idaabobo ti wọn ti pin yii pada lẹyin ti NDA kọwe si wọn lọgbọn ọjọ oṣu kẹwaa fi sọ pe ipele meji ninu awọn rọba idaabobo wọnyii ko ba gbendeke amuyẹ to yẹ ki rọba idaabobo n ni.
Ajọ Marie Stopes ni awọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ NDA lati tete ṣe iwadii nkan to ṣẹlẹ si awọn ipele wọnyii ati ọna lati tun jẹ ki wọn daa sii.
Marie Stopes ṣalaye siwaju pe awọn ni idaniloju pe ipele meji naa ni to paali rọba idaabobo ojilelọọdunrun o dín marun un ni eyi to le ni miliọnu kan rọba idaabobo kọọkan.
Won ni awọn ti ri to idaji rẹ gba pada bayii.













