Ahmed Lawan: Kó sí ǹkan tí Ààrẹ Buhari yóò fẹ́, tí mí ò ní ṣe fun

AHMED LAWAN

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Agbẹjọ́rọ̀ Sulaiman bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Ahmed Lawan sọ pé òun kòní tako ààrẹ lórí ohunkohun.

Agbẹjọrọ Sulaiman Abaya ti ni idoju ofin bolẹ ni ọrọ ti Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Ahmed Lawan sọ pe ko si ohunkohun ti Aarẹ Buhari ba ti gbe wa si iwaju oun.

Ahmed Lawan sọ eyi lasiko ti Alaga Ajọ to n gba Aarẹ Buhari ni iyanju lori ọrọ iwa ajẹbanu, Ọjọgbon Itse Sagay ṣe abẹwo si ni ọfiisi rẹ ni Abuja.

Agbẹjọro Abaya ni ọrọ Aarẹ Ile Igbimọ Asofin naa ko bojumu nitori ijọba tiwantiwa faaye fun Ile Igbimọ Asofin lati ma a ṣe ofintoto lori ohunkohun ti aarẹ ba fẹ ṣe.

O ni awọn asofin ati aarẹ gbọdọ wo ohun gbogbo ti aarẹ ba gbe wa ni ẹẹmeji, ki wọn le wo o boya o ba ofin mu, abi boya o ba eto awọn araalu mu.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Agbẹjọro Sulaiman Abaya fikun un wi pe ki ilọsiwaju le ba eto aabo orilẹ-ede Naijiria, pẹlu ilọsiwaju to muna doko, wọn gbọdọ ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ẹka to n bojuto ifẹ ara ilu.

Agbẹjọro naa rọ awọn asofin naa lati ranti wi pe ipo agba ni Naijiria wa, nitori naa ki wọn jẹ apẹrẹ rere fun awon orile-ede miran to wa ni Afrika.

wo ẹẹmẹta ti Ile Igbimọ Asofin labẹ adari Ile Igbimo Asofin tẹlẹri, Bukola Saraki kọ̀ lati buwọlu aba aarẹ Buhari

  • Ile Igbimọ Asofin Agba da eto isuna ẹka ijọba to n risi ọrọ karakata (trade and investment) to le ni biliọnu mẹẹdogun, N15.63 billion danu fun ọdun 2019.
  • Bakan naa ni Bukola Saraki lasiko rẹ kọ lati buwọlu Ibrahim Magu gẹgẹ bi adari ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC nitori wọn ko gba ọrọ to ba ofin mu.
Àkọlé fídíò, Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá
  • Ọdun 2016 ni Saraki kọ lati buwọlu Aliyu Saidu Abubakar gẹgẹ bi aṣoju kun idibo ila oorun ariwa orilẹ-ede Naijiria ni ẹka ibanisọrọ orilẹ-ede Naijiria, NCC ni ọdun 2016,
  • Amọ ni bayii, Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Ahmed Lawan ti wa buwọlu yiyansipo arakunrin naa.
Àkọlé fídíò, Ẹ wo fídíò Kìnìhún ní ibùgbé rẹ̀ tuntun ní Bogije, Lekki