Àbá ìsúná N1.3 trillion ni CBN gbé jáde fún ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Alaga Ile Igbimọ Asofin lori ọrọ to jẹ mọ ile ifowopamọsi ati owo ile wa, Victor Nwokolo le awọn akọroyin jade lasiko ti banki apapọ Naijiria n ṣalaye eto iṣuna wọn.
Eto aba iṣuna ile iṣẹ banki apapọ, CBN le ni tiriliọnu kan naira fun ọdun 2020.
Iroyin ni wọn ni ki awọn akọroyin yẹba fun ile ki wọn to jiroro lẹkunrẹrẹ lori abadofin ti banki Naijiria gbe wa siwaju ile naa.
Ogbeni Adamu Edward Lametek lo ṣoju fun gomina Godwin Emefiele, oun lo wa sọ bi banki apapọ yoo ṣe naa owo iṣuna naa.
Asofin Nwokolo to ṣaaju igbimọ lori banki ati owo Naijiria ni ki awọn oṣiṣẹ to jẹ oluranlọwọ naa jade lasiko naa.
Aṣofin Gudaji Kazure lọsẹ to kọja ti kọkọ bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iye owo ti wọn kọ fun eto iṣuna naa, to ni iye owo naa ti pọju paapaa lasiko yii.










