ODF Law: Ààrẹ Buhari ní àṣà ṣíṣe igá lójú táyé yóò di ọ̀rọ̀ ìtàn láìpẹ́

Ọmọdekunrin to n se igbọnsẹ soju odo

Oríṣun àwòrán, Unicef

Yoruba ni ilu ti ko ba si ofin, ẹsẹ ko si nibẹ, lati ọdun 2025 lọ, o ti di eewọ fun ẹnikẹni lorilẹede Naijiria lati yagbẹ si ibikibi to ba wu.

Idi ni pe aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu ofin kan lọjọru eyi to ni o ti di eewọ lati maa yagbẹ kiri igboro lati ọdun 2025 lọ.

Ofin naa, ti wọn pe ni Executive Order 009 si nireti wa pe yoo fi opin si asa kawọn ọmọ Naijiria maa dawọ tẹlẹ laarin ilu lai lo ile iyagbẹ rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye ohun ti ofin 009 ọhun da le lori, Buhari ni ofin ti ileesẹ to n se akoso awọn ohun alumọọni inu omi gbe kalẹ yii, lawọn ẹka mii to ni nkan se pẹlu ọrọ ayika yoo gbaruku ti ko lee fidi mulẹ.

Ọmọdekunrin to n se igbọnsẹ soju odo

Oríṣun àwòrán, Unicef

Bakan naa ni ofin tuntun ọhun ti ro ileesẹ to wa fọrọ ohun alumọọni inu omi lagbara lati ri daju pe ileesẹ ijọba kọọkan, ileewe, ile itura, ileepo, ibudo ijọsin, awọn ọja gbogbo, ile iwosan ati awọn ọọfisi gbogbo ni anfaani si ile igbọnsẹ abi salanga ni ayika wọn.

Bakan naa nile asofin apapọ ati tawọn ipinlẹ yoo gbe ofin miran kalẹ eyi ti yoo koro oju si iwa sise igbọnsẹ saarin igboro pẹlu ijiya to tọ ati owo itanran to yẹ lori ẹsẹ naa.