Kogi Election: Dino Melaye fẹ́ mọ bí ayédèrú ọlọ́pàá ṣé borí ọlọ́pàá gidi lásìkò ìdìbò Kogi

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Oludije fẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo atundi Sẹnẹtọ fun ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Kogi, Dino Melaye ti ko ẹri lọ ba ajọ eleto idibo INEC lati ṣafihan magomago to waye lasiko idibo Kogi laipẹ yii.
Lọjọru ni Dino Melaye lọ pade oludari agba fẹka iroyin ati idanilẹkọ awọn oludibo labẹ ajọ INEC, Ọgbẹni Festus Okoye, ti o si gbe awọn ẹri naa to wa lori fọnran fidio DVD mọkanlelogun le lọwọ.
Dino Melaye ni pẹlu ẹri ti oun mu wa yii, ohun ti oun fẹ ni ki INEC wọgile idibo to waye naa.
Bakan naa lo fi iwe ifẹhonuhan tẹle awọn ẹri to mu wa, eleyi ti agbẹjọro rẹ, Tobechukwu Nweke buwọlu.
Lara ohun to sọ ninu iwe ẹsun rẹ ni pe ''iwa janduku, jiji apoti idibo gbe ati awọn aiṣedeede mii waye lasiko idibo naa, to fi mọ iwa ipaniyan, ti mo si fi ẹri rẹ sinu fọnran fidio ti mo mu wa, mo si n parọwa si INEC lati wọgile idibo naa''

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Melaye tun bẹnu atẹ lu ọrọ ọga ọlọpaa Naijiria to sọ pe awọn oloṣelu lo ran asọ fawọn ayederu ọlọpaa to da ibo ru lawọn ibi kan ni Bayelsa ati Kogi.
Dino Melaye ni, ti iru nkan bayi ba ti n ṣẹlẹ ni Naijiria, ko si ireti pe aabo to peye le e wa fara ilu.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Awọn oṣiṣẹ ajọ INEC to gba iwe ẹsun ati ẹri to muwa lọwọ rẹ sọ fun pe, awọn yoo ṣe ayẹwo iwe ẹsun to mu wa naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo fídíò Kìnìhún tí wọ́n mú l'Eko ní ibùgbé rẹ̀ tuntun, Bogije, Lekki
- Wo bí àwọn adigunjalè ṣe sọ Tomi Waziri onítaasín di afọ́jú lójijì!
- Àwọn ọnà ti Olusegun Aroke ń gba wọ́'ke owó nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n rèé
- Seyi Makinde kò leè gba adé lórí àwa ọba 21, iléẹjọ́ ni yóò là wá níjà - Lekan Balogun
- Oríṣìí ajá mẹ́wàá tó léwu rèé, tí ẹ kò leè sìn nínú ilé
- Goodluck Jonathan jẹ́ olùfọkànsìn àti ìwúrí fún ìrandíran ní Nàìjíríà - Buhari
INEC ti ṣaaju kede pe idibo ipo Sẹnẹtọ ti Dino Melaye ati Smart Adeyemi ti ẹgbẹ APC dijọ du ko kẹsẹjari.
Ajọ INEC naa ni nitori idi eyi, atundi ibo yoo waye lawọn ibi ti kudiẹ kudiẹ ti waye lasiko idibo.












