Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá di ẹ̀bi rògbòdìyàin ní Kogi ru ìwà kòtọ́ àwọn olóṣèlú

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko din ni eeyan mejilelogun ni ọwọ ti tẹ lori rogbodiyan to waye lasiko idibo nipinlẹ Kogi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lo ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n sọrọ lori ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria lalẹ ọjọ Satide lẹyin ti ibo didi pari lawọn ipinlẹ mejeeji.
- Ẹ̀rù kò bà mí láti padà sí Bolivia- Evo Morales
- Ọlọpàá gba owó ilé ìwé #150,000 lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ DELSU kan
- Olùdíje 24 ni yóò kópa ní ìdìbò Kogí
- Kò sí aàyè fún ìbò rírà àti títà ni Kogi àti Bayelsa- IGP
- Irọ́ ni pé wọ́n sèkọlù sí Gómìnà Seyi Makinde - Ọlọ́pàá Kogi
- Kàyéfì rèé! Aṣẹ́wó rán awakọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ l'ẹ̀wọ̀n
Bakan naa lo ni ọkọ kan tawọn janduku fẹ fi lọ hu iwa laabi wọn lagbegbe kan ni Kogi lọwọ awọn ọlọpaa tun tẹ.
O fi kun pe oniruuru ibọn pẹlu ọkẹaimoye ọta ibsn ni wọn tun gba lọwọ awọn ọdaluru kan nipinlẹ naa.
Ọga ọlọpaa Frank Mba ni awọn oloṣelu pẹlu iwa booba o pa, boo ba o bu u lẹsẹ ati iwa afemi-afemi wọn lo fa gbogbo rukerudo to waye lasiko idibo ni ipinlẹ mejeeji, paapaajulọ nipinlẹ Kogi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ko si aniani pe eto idibo gomina nipinlẹ Kogi gbomi lara awọn agbofinro ju ti ipinlẹ bayelsa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni lootọ ni awọn ṣe ifimufinlẹ to munadoko ṣaaju idibo naa lati ms ibi ti eefin wahala lee ti ru lasiko idibo naa sibẹ ohun to waye kii ṣe eyi ti wọn lee maa dẹbi rẹ ru awọn agbofinro bi o ti wulẹ o mọ. O ni ka ni kii ṣe bẹẹ ni, ohun ti o ṣẹlẹ ko ba buru ju bi o ti ri naa lọ.
Nigba to n dahun ibeere lori iye eeyan to ku lasiko idibo ni ipinlẹ Kogi, lẹyin ti iroyin fi idi rẹ mulẹ pe eeyan mẹta lawọn afunrasi janduku kan ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa yinbọn pa lasiko idibo naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria naa ni oun ko tii le sọ ni pato iye awọn eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko idibo naa.













