Kogi election: Kò sí aàyè fún ìbò rírà àti títà ni Kogi àti Bayelsa- IGP

Oríṣun àwòrán, @inec
Oga agba awọn ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu lo fi ọrọ yii sita pe ko ni si aaye fun magomago kankan lasiko eto idibo to m bọ yii.
O ni oun n kilọ fawọn to ba n gbero lati fa wahala kankan lasiko idibo sipo gomina to m bọ lọna ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla ti a wa yii ni eto idibo naa yoo waye.
Adamu sọrọ yii lasiko ipade apapọ fawọn to maa ṣiṣẹ lasiko idibo naa ni olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo INEC ni Abuja.
Adamu Mohammed ni ọwọ ofin yoo mu ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati ta tabi ra ibo gomina ni ipinlẹ mejeeji ti idibo ti m bọ lọna.

Oríṣun àwòrán, @kola
Lasiko idibo apapọ ni Naijiria to waye loṣu keji ọdun yii ni INEC ti ni awọn ri iṣoro yii ni awọn ipinlẹ kan ni eyi ti wọn ti ṣiṣẹ gbogun ti bayii.
Elomii to tun wa nibi ipade gbogboogbo fawọn oṣiṣẹ ti ọrọ kan naa ni Ojọgbon Mahmood Yakubu to jẹ ọga agba fun ajọ eleto idibo ni Naijiria.
Mahmood Yakubu ni awọn ipinlẹ mejeeji lo ti n ri iṣẹlẹ awọn to n niwa ipa nibi ti aya awọn mii ti fẹ maa ja.
O ni awọn iwadii wa ti foju awọn agbegbe to ṣeeṣẹ ki wahala wa han wa ni eyi ti a ti n siṣẹ le lori bayii.

Oríṣun àwòrán, @Nigeria police
Ati pe , a ti kẹkọọ siwaju lẹyin idibo oṣu keji ọdun yii ni eyi ti a fi ni idaniloju pe a maa ṣe iṣẹ to dara ju tatẹyinwa lọ.
Igbaradi to ti wa nilẹ bayii:
Adamu ṣalaye pe ọlọpaa mọkanlelogoji le ni ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn lo maa ṣiṣẹ ni ipinlẹ Bayelsa.
Nigba ti igba le ni ẹgbẹrun marundinlogoji agbofinro a ṣiṣẹ ni ipinlẹ Kogi lasiko idibo naa.
Adamu ni awọn agbofinro ti ṣetan lati pese aabo to peye fawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ati awọn oludibo ninu ipinlẹ mejeeji.
O ni oun gbe igbesẹ yii lataari ki awọn to maa kopa ninu eto idibo naa le ṣe oun to yẹ lasiko laisi magomago ni.
Bakan naa ni awọn agbofinro a pese eto aabo fawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ to maa ṣiṣẹ lasiko idibo naa ati ni ibudo banki Naijiria ati olu ile iṣẹ INEC lawon ipinlẹ mejeeji














