Dino Melaye: Àyà mi kò já lórí ìdájọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí rárá

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, Ko sewu loko, afi giri aparo lorin ti Dino n kọ

Agbẹnusọ fún Dino Melaye ti sọ pé àyà Sẹnetọ ọ̀hún kó já lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè lòdì sí ìdajọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́sùn ìdìbò.

Dino Melaye ti sọ pe ẹru ko ba odo oun, lori ẹjọ kotẹmilọrun to pe tako idajọ to da ibo rẹ sile igbimọ aṣofin agba ni iwọ oorun ipinlẹ Kogi nu.

Samuel Gideon tó jẹ́ àgbénusọ fun Dino Melaye to wọle idibo sipo sẹnetọ fun ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kogi ṣalaye pé ẹru ko bodo Dino.

Nigba ti Gideon n ba BBC sọrọ lori ọrọ Adajọ Abubakar Datti Yahaya to dari eto igbẹjọ ọhun nile ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin igbẹjọ lo sọ ọrọ yii.

AdajọYahaya ni ile ẹjọ yoo kan si Dino Melaye ati Adeyẹmi Smart to ba jẹ ni ti Dino ni "Ọkan ọmọ Ọlọrun balẹ."

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, Bi wọn dibo nigba igba, Dino ni oun ni yoo wọle

Gideon sọ pe "A mọ pe Dino lo wọle ninu idibo naa, fun idi eyii, aya Dino ko ja."

O tẹsiwaju pe "Ti wọn ba tun ibo naa di nigba ẹgbẹrun meji, Dino lo maa wọle."

Gideon ṣalaye pe ipinnu Dino ni lati mu idagbasoke wa si ipinlẹ Kogi, lori awọn ohun amayedẹrun bi ọna to ja geere, omi ati ina ijọba.

Ṣaaju ni Dino ti gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, lẹyin ti ile ẹjọ to n gbẹsun idibo da ibo rẹ nu, to si kede Smart Adeyemi gẹgẹ bi ojulowo ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, Ko sewu loko, afi giri aparo lorin ti Dino n kọ

Sugbọn ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa l'Abuja ti ni oun yoo ṣe idajọ laipẹ.

Abubakar Datti Yahaya to n risi ipẹjọ naa kede pe, oun yoo fi to awọn ti ọrọ naa kan ti asiko ba to.

Idakeji ti idajọ Adajọ naa le ja si yatọ si pe ki o kede ọkan ninu awọn oludije mejeeji ni pe ki Adajọ kede pe ki wọn tun ibo ẹkun yii di lẹẹkeji ki idaniloju ẹni to yege le wa.

Àkọlé fídíò, Dino Melaye nánwó fún Ayefẹlẹ lójú agbo
Àkọlé fídíò, Sport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́...