Festus Keyamo paradà, ó di mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́

Festus Keyamo pẹlu Chris Ngige

Oríṣun àwòrán, @fkeyamo

Wọn ti gbe minisita abẹle fun idagbasoke agbegbe Niger delta, Festus Keyamo kuro lọ si ileeṣẹ ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ.

Atẹjade kan to jade lati ọfiisi akọwe ijsba apapọ orilẹede Naijiria, ṣalaye peKeyamo yoo lọ rọpo Tayọ Alaṣọadura, ti alaṣọadura yoo si kọri si ileeṣẹ idagbasoke agbegbe Niger/Delta.

Atẹjade naa fi kun un pe Aarẹ Buhari ti buwọlu iṣipopada yii.

Titi di asiko yii, Sẹnetọ Tayọ Alaṣọadura ni minisita kekere fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ.

Aṣẹ yii bẹrẹ si ni fidi mulẹ lati ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan ọdun 2019